Obi le di aarẹ Naijiria lọdun 2027-Tanko

Monisọla Saka

Adari apapọ fun ikọ Obidient Movement, ti i ṣe ẹgbẹ awọn ti wọn n ṣatilẹyin fun Peter Obi, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Anambra, ti o si tun jẹ ọkan ninu awọn to dije sipo aarẹ lọdun 2023, Yunusa Tanko, ti ni o ṣee ṣe ki Peter Obi wọle ibo aarẹ ọdun 2027, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

O ni ti ki i baa ṣe ti ọwọ ojooro ti wọn ti bọ eto idibo ọdun to kọja ni, ko sohun to ni ki Obi ma wọle, ati pe ilẹ Naijiria tuntun ṣee ṣe, tawọn eeyan ba dibo yan adari gidi sipo.

Nibi ipade apero ọlọjọ kan ti wọn pe ni ‘Ṣiṣe atunṣe ọtun fun awọn ọmọlẹyin Obi fun ipa rere’ (Repositioning the Obidient Movement for Greater Impact), tawọn Obidient Movement atawọn ẹgbẹ alatilẹyin ipinlẹ Anambra (Anambra State Support Groups), ṣagbekalẹ rẹ, ni gbọngan ile ijọsin All Saints Cathedral Auditorium, Onitsha, nipinlẹ Anambra, lo ti sọrọ naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Tanko ni, “Ohun ti o jẹ wa logun ni pipolongo ijọba rere ati iṣedeede nipa pipe awọn eekan pataki papọ lati jiroro lori ọjọ ọla Naijiria.

Eto yii wa fun erongba ẹgbẹ yii lori iṣọkan, idajọ ododo ati eto ori-o-jori.

“Gbogbo nnkan to ṣee ṣe lati mu ki Obi di Aarẹ Naijiria lọdun 2027, ni oun funra ẹ ni, ta a ba le fimọ ṣọkan. A maa jẹ ki awọn aṣoju wa ti wa ni imurasilẹ daadaa ko too di asiko ibo gbogbogboo ọdun 2027, pẹlu oriṣiiriṣii eto ikọni.

“Ilẹ Naijiria ọtun ṣee ṣe ko waye, ti a ba bẹrẹ si i ṣe awọn ohun to tọ nipa yiyan awọn ti yoo jẹ adari fun wa. A duro lori pe a fẹẹ fopin sijọba buruku ni Naijiria nipa fifi ibo gbe awọn to yẹ sipo. Lasiko ibo apapọ ọdun 2023, wọn fẹsun kan wa pe a ko ni eto, ile ẹgbẹ atawọn nnkan mi-in, sibẹ, Peter Obi jawe olubori, ṣugbọn wọn gbegi dina rẹ nipasẹ iwa magomago ti wọn ti bọ eto idibo naa. Amọ lọtẹ yii, iru ẹ ko tun ni i waye mọ.

“Koda inu awọn eeyan apa Ariwa gan-an ko dun siru ijọba to wa nipo. A maa pe fun atunṣe lẹka ajọ eleto idibo, a si maa bori lojukoroju, ati nipasẹ ofin. “.

Bakan naa ni Tanko tun dabaa pe ko yẹ ko jẹ lati ọdọ Aarẹ, ni iyansipo alaga ajọ eleto idibo yoo ti maa wa, lati le ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ laaye ara wọn.

Leave a Reply