Obinrin di ọga agba patapata ni yunifasiti LASU fungba akọkọ

Ọjọgbọn Ibiyẹmi Ọlatunji-Bello to jẹ iyawo Kọmiṣanna fun eto ayika nipinlẹ Eko, Ọlatunji Bello, ni wọn ti yan bayii gẹgẹ bii ọga agba patapata fun ileewe giga yunifasiti  ijọba ipinlẹ Eko, LASU.

Obinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọta yii ti wa ni ipo yii gẹgẹ bii adele ọga agba, ki wọn too waa yan an gẹgẹ bii ọga agba pata.

Pẹlu ipo tuntun to di mu yii, oun ni obinrin akọkọ ti yoo kọkọ wa niru ipo yii nileewe naa, oun naa si ni olori ileewe giga Fasiti ipinlẹ Eko yii kẹsan-an. Imọ nipa iṣegun oyinbo ni obinrin naa gba oye le lori.

Leave a Reply