Obinrin jayejaye kan to n lu awọn eeyan ni jibiti kiri Ibadan yoo foju bale-ẹjọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Yoruba bọ wọn ni, ọjọ gbogbo n tole, ọjọ kan bayii ni tolohun. Owe yii lo ṣẹ mọ obinrin ọmọ jayejaye kan n’Ibadan, Ajayi Oluwabukọla Temitọpẹ, pẹlu bọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo olowo baṣubaṣu ( EFCC), ẹka tilu Ibadan, ṣe tẹ ẹ lẹyin ti wọn lo ti lu ọkẹ aimọye eeyan ni jibiti.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, wọn ni obinrin ẹni ọdun mejilelogoji (42) yii ti lu awọn eeyan ni jibiti owo to to milliọnu mẹẹẹdọgbọn Naira (N25m).

 

Wilson Uwajaire ti i ṣe agbẹnusọ fajọ EFCC fidi ẹ mulẹ ninu atẹjade naa pe oriṣiiriṣii iwe ẹsun lawọn eeyan ti kọ si ajọ naa nipa Temitọpẹ ko too di pe ọwọ awọn agbofinro ba a lẹyin ọpọlọpọ iwadii.

Wọn ni niṣe lo maa n dibọn bii oniṣowo pataki lati lu awọn eeyan ni jibiti owo nla nla.

A gbọ pe bo ṣe lu oniṣowo ọti ẹlẹrindodo kan to ni ileetaja niluu Ibadan ati Sokoto, nilẹ Hausa lọhun-un, Ọgbẹni Basiru Musa, ni jibiti owo to le diẹ ni miliọnu meje ataabọ Naira pẹlu bo ṣe pera ẹ loniṣowo to n ta ọti fawọn alaratunta.

Ṣugbọn jagunlabi kan gbowo lasan ni, ko gbe ọja kankan fun wọn, nigba ti ko si kuku ni ọti kankan to n ta nibikan.

Eyi lo jọ pe obinrin alafẹ naa fi ṣaṣemọ iwa jibiti rẹ nitori ko pẹ ti Ọgbẹni Musa fẹjọ ẹ sun ajọ EFCC ni wọn mu un.

Ṣaaju eyi lobinrin ẹni ọdun mejilelogoji yii ti lu ileetaja ọti kan ti wọn n pe ni Mabera Trading Company, niluu Sokoto, ni jibiti owo to le ni miliọnu mẹtadinlogun Naira (17m) pẹlu bo ṣe ṣadehun lati ta ẹkun ọkọ tirela ọti kan ti apapọ owo ẹ le ni miliọnu mẹtadinlogun Naira (N17m) fun wọn, ṣugbọn to jẹ pe ṣe lo kan gbowo awọn eeyan naa lasan.

Laipẹ rara lobinrin naa yoo foju bale-ẹjọ gẹgẹ bi agbẹnusọ awọn EFCC ṣe fidi ẹ mulẹ.

Leave a Reply