Obinrin kan padanu ẹmi rẹ, awọn ọmọde mẹta fara pa, ninu ijamba mọto lọjọ ọdun tuntun n’Ikire

Florence Babaṣọla

Agbẹnusọ ẹṣọ ajọ ojupopo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ti fidi rẹ mulẹ pe obinrin kan lo jade laye, nigba ti awọn ọmọde mẹta fara pa yanna-yanna nibi ijamba mọto to ṣẹlẹ niluu Ikire lọsan-an ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun tuntun yii.

Ogungbemi ṣalaye pe ere asapajude ti mọto akoyọyọ kan ati Toyota Corolla kan sa pade ara wọn lo fa ijamba naa.

 

O ni ṣe lawọn ọkọ mejeeji sọ ijanu wọn nu, ti wọn si fori sọ ara wọn. Eeyan mẹrin lo fara pa; obinrin kan atawọn ọmọde mẹta.

 

ALAROYE gbọ pe wọn gbe obinrin naa lọ sileewosan Ọbafẹmi Awolọwọ University Teaching Hospital, Ile Ifẹ, ṣugbọn ko pẹ ti wọn gbe e debẹ lo jade laye.

 

Awọn ajọ O’Ambulance la gbọ pe wọn kọkọ ṣetọju awọn ọmọde keekeeke naa, ki wọn too gbe wọn lọ sileewosan fun itọju.

Leave a Reply