Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Titi di asiko ti a n kọ iroyin yii, wọn ko ti i ri mọto Toyota Camry kan to ko sinu odo Ọṣun to wa lagbegbe Gbodofọn, niluu Oṣogbo, yọ.
Amọ sa, ori ko obinrin kan to wa mọto naa yọ nitori bo ṣe ko sinu ẹ ni awọn ti wọn mọ odo o wẹ lagbegbe naa bẹ somi, ti wọn si lọọ fa a yọ ninu mọto nisalẹ odo.
Agbegbe Ogo-Oluwa la gbọ pe obinrin naa ti n bọ ni nnkan bii aago mejila ọsan ku iṣẹju mẹwaa lọjọ Abamẹta, Satide. Awọn ti wọn wa leti odo sọ pe ṣọọbu mẹkaniiki kan lo ti n bọ.
Bo ṣe ku diẹ ko de ori biriiji odo naa la gbọ pe o sọ ijanu ọkọ rẹ nu, gbogbo awọn ti wọn n kọja lọ lagbegbe ọhun ni wọn n sa kabakaba ko too di pe o lọọ ko sinu odo.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro fun ajọ panapana nipinlẹ Ọṣun, Ibrahim Adekunle, sọ pe obinrin to wa mọto naa ko fara pa, ati pe o ti wa nileewosan kan fun ayẹwo to tọ bayii.
Adekunle ni igbiyanju ti n lọ lọwọ lati yọ mọto rẹ ninu odo bo tilẹ jẹ pe omi pọ nibẹ bayii latari ojo to n fi gbogbo igba rọ.