Obinrin meji ku ni Fidiwọ, dẹrẹba ọkọ wọn lo sare asaju

 Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Bi awọn ẹṣọ alaabo oju popo ṣe n kilọ ere asapajude to, awọn awakọ kan ko gba si wọn lẹnu. Iru ẹ ni ti iṣẹlẹ to fa iku ojiji fawọn obinrin meji laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Dẹrẹba lo n sare asaju, lo ba fọna silẹ, nigba ti mọto takiti lo ko si koto to ku fun ira, bawọn obinrin naa ṣe dero ọrun niyẹn.

Nnkan bii aago mọkanla kọja ogun iṣẹju ni ijamba yii waye lagbegbe Fidiwọ, ni marosẹ Eko s’Ibadan, gẹgẹ Babatunde Akinbiyi,Alukoro TRACE, ṣe ṣalaye.

Akinbiyi sọ ọ di mimọ pe mọto to ni aaye daadaa ni bọọsi YEE 202 XA ti ijamba ṣẹlẹ si yii. O ni eeyan meje lo wa ninu ẹ lasiko ijamba naa, awọn obinrin agbalagba mẹrin ati ọmọdebinrin kan, bẹẹ lawọn ọkunrin meji naa wa nibẹ pẹlu.

Ere to pọ ju ti dẹrẹba wọn n sa lo fa a ti nnkan fi daru mọ ọn lọwọ, to jẹ niṣe lo ya kuro loju ọna, ti mọto naa takiti, to lọọ kori bọ koto giriwo kan to jẹ ira lo wa nibẹ, bo ṣe di pe awọn iyaale ile meji doloogbe loju-ẹsẹ niyẹn.

Eeyan mẹrin lo tun farapa, gbogbo wọn ni wọn ko lọ si ọsibitu Victory, l’Ogere. Mọṣuari FOS, n’Ipara-Rẹmọ, ni wọn gbe oku awọn iya meji naa lọ ni tiwọn.

TRACE ba ẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn kẹdun, bẹẹ naa si ni wọn tun ranṣẹ ikilọ sawọn awakọ ti ki i gba imọran, pe ki wọn yee ran alaiṣẹ sọrun ọsan gangan.

Leave a Reply