Obinrin meji lo wa ninu awọn ikọ adigunjale ti wọn mu l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti  

Awọn meje kan, ninu eyi ti obinrin meji wa, ti ha sọwọ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti bayii fun ẹsun idigunjale. Awọn eeyan naa ni wọn sọ pe wọn da awọn arinrin-ajo lọna ni titi marosẹ Aisẹgba si Ilumọba, nijọba ibilẹ Gbọnyin, laipẹ yii.

Awọn afurasi ọhun ni Solomon Alexander, Eric Tile, Promise Shea, Desmond Peter, Peter Ayo, Ayangbe Blessing ati Jennifer Allah.

ALAROYE gbọ latọdọ awọn ọlọpaa pe ọjọ kẹjọ, oṣu to kọja, lawọn kan ti wọn fi aṣọ boju ko igi di oju ọna Aisẹgba si Ilumọba, bẹẹ ni wọn ko ibọn ati ada dani, wọn si ja awọn eeyan lole.

Lasiko naa ni wọn gba ẹgbẹrun lọna ojilelẹẹẹdẹgbẹta naira (N540,000), kọmputa alaagbeletan towo ẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira (N80,000), foonu Sico to jẹ ẹgbẹrun mẹfa naira (N6,000) ati foonu Hi-Mobile towo ẹ to ẹgbẹrun mẹta naira (N3,000).

Lẹyin iṣẹlẹ naa lawọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale (SARS) bẹrẹ si i wa ikọ ọhun kiri kọwọ too tẹ Solomon, oun lo si ṣokunfa bi wọn ṣe mu awọn to ku.

Awọn ọlọpaa ni awọn ri ibọn ilewọ oyinbo kan, ibọn ibilẹ meji, ibọn onigi, ada, aake atawọn nnkan ija oloro mi-in gba lọwọ awọn eeyan naa.

Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ, Solomon ni loootọ lawọn lọọ digun jale, awọn to si fura si oun lẹyin iṣẹlẹ naa ni wọn lọọ sọ fawọn ọlọpaa ti wọn fi mu oun. O ni awọn ni ọga kan to ti sa lọ, ọwọ ẹ si ni gbogbo awọn nnkan ija oloro tawọn n lo wa, ṣugbọn ile awọn mẹta ninu ikọ naa lawọn ọlọpaa ti ba awọn ibọn ti wọn gba lọwọ awọn.

Bakan naa lo ni ọrẹbinrin ohun ni Jennifer, nigba ti Blessing jẹ ọrẹbinrin ọga awọn to sa lọ, ṣugbọn awọn mejeeji ko ba awọn jale.

Ọmọ ipinlẹ Benue ni Blessing, alaye to si ṣe ni pe oun kan lọọ ki ẹnikan lawọn ọlọpaa mu oun, ti wọn si sọ pe adigunjale loun kọrọ too di ti SARS. Alaye kan naa ni Jennifer ṣe, ṣugbọn awọn mejeeji pada jẹwọ pe iṣẹ aṣẹwo lawọn n ṣe, awọn si mọ awọn afurasi to ku, ṣugbọn awọn ko mọ pe adigunjale ni wọn.

Ninu ọrọ Promise, o ni igba akọkọ toun ba wọn lọ soko ole ni eyi to jẹ kọwọ tẹ awọn yii, ati pe Solomon lo waa ba oun atawọn to ku pe awọn ọmọ ikọ oun ko si nitosi, kawọn ran oun lọwọ lati ja awọn eeyan lole.

O ni ọmọ ipinlẹ Benue lawọn, iṣẹ lebira lawọn si n ṣe ki Solomon too waa ba awọn.

Eric naa sọrọ, o ni Solomon lo da ikọ naa silẹ, o si ti kọkọ waa ba awọn pe kawọn darapọ. O ni nigba to pada wa, o ni oun ti ja awọn eeyan lole owo to le lẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ati kọmputa agbeletan, ati pe mẹrin lawọn ọmọ ikọ naa, ṣugbọn awọn mẹta to ku ti rin irin-ajo.

O ṣalaye siwaju pe aburo oun ni Desmond, oun si ni Solomon kọkọ waa ba, bẹẹ lo sọ pe oun (Eric) jọ ẹni to le lọọ sọrọ fawọn ọlọpaa nipa iṣẹ toun fẹẹ gbe fun awọn, ṣugbọn Desmond fi i lọkan balẹ pe oun ki i ṣe ọdalẹ. Lẹyin eyi lo ni Solomon ko awọn lọ sile Promise, nibẹ loun si ti ri awọn ọmọ ikọ to ku kawọn too ṣeto idigunjale naa.

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe awọn eeyan naa yoo foju bale-ẹjọ nigba ti iwadii ba pari laipẹ.

Leave a Reply