Obinrin mejila lo wa ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹrindinlọgọta to sakolo ọlọpaa l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ko din ni aadọta (50) awọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun ti wọn tun n digunjale lagbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko, tọwọ awọn agbofinro tẹ lopin ọsẹ yii. Bẹẹ lọwọ tun ba awọn mẹfa mi-in lagbegbe Lẹkki, ọmọ ẹgbẹ okunkun ati janduku ni wọn pe awọn eleyii naa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde yii.

Wọn ni lati ọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn ti ko si fifi pampẹ ọba gbe awọn afurasi ọdaran ti ko jẹ kawọn eeyan ilu Ikorodu nifọkanbalẹ ọhun, nigba to si fi maa di owurọ ọjọ Aiku, ilẹ ti wẹ, ọkunrin mejidilogoji (38) ati obinrin mejila (12) ti ko si wọn lọwọ. Lara awọn ileto tawọn afurasi naa sa pamọ si ni Imọta, Igbokuta, Adamọ, Emure, lagbegbe Ikorodu, gbogbo agbegbe yii ni wọn lawọn ọlọpaa gbọn yẹbẹyẹbẹ.

Islamiya Salisu, obinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, wa lara awọn obinrin tọwọ ba, wọn lawọn ba ibọn ibilẹ kan ati ọta ibọn lọwọ ẹ l’Emure, wọn loun niyawo Nọmba waanu, Nọmba waanu ni wọn maa n pe olori ẹgbẹ okunkun ti ‘Aiye’.

Bakan naa ni wọn mu Iyabọ Gbamila, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, iyawo olori ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ ni Igbokuta loun, wọn ba ibọn oyinbo kan ati awọn ọta ibọn lọwọ ẹ.

Lara awọn gende tọwọ ba ni Abiodun Abbey tawọn eeyan mọ si ‘Oju Ogun le,’ wọn lo ti paayan to ju mejilelogun lọ lagbegbe Ikorodu, wọn latamatase ni laarin awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun agbegbe naa. Ọwọ si tun ba Dosunmu Oluwaṣeun, ẹni ogun ọdun, Ṣẹgun Adelaja, ẹni ọdun mejilelogun, atawọn mi-in.

Lagbegbe Lẹkki, ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹfa ti tawọn ọlọpaa teṣan Ẹlẹmọrọ mu ni: Hassan Adeyẹmi, Yusuf Adesoye, Yusuf Sadiku, Monsuru Ojo, Ramon Tajudeen ati Ismaila Adebanjo. Ismaila yii ni wọn pe lolori ẹgbẹ ‘Aiye’ lagbegbe Lẹkki, wọn ni tẹwọnde ẹda kan ni, aipẹ yii ni wọn tu u silẹ lọgba ẹwọn tile-ẹjọ ju u si lọdun diẹ sẹyin.

Lara awọn nnkan ija oloro ti wọn ka mọ awọn tọwọ ba wọnyi lọwọ ni fila bẹrẹẹti ti wọn kọrukọ ẹgbẹ ‘Aiye’ si, awọn ibọn, ọta ibọn ati katiriiji ti wọn n ko ọta si, awọn nnkan eelo ẹgbẹ okunkun, ati oogun abẹnugọngọ loriṣiiriṣii.

Odumosu ni paa-paa-pa lawọn maa ṣe iṣẹ iwadii lori awọn afurasi ẹlẹgbẹkẹgbẹ wọnyi, o si paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo wọn lọ sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, ibẹ ni wọn wa lọwọlọwọ, ibẹ si ni wọn maa gba de kootu laipẹ, gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply