Ọbinrin ti Robbinson fipa ba lo pọ loṣu kẹrin ko ti i gbadun

*Wọn ni eegun ẹyin rẹ ti kan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Igbobi, l’Ekoo, ni wọn ni ọmọ ti afipabanilopọ kan, Robbinson Goddey, ba lo pọ loṣu kẹrin, ọdun yii, ṣi wa titi di asiko ta a n kọ iroyin yii. Ibẹ lo ti n gbatọju nitori ẹyin rẹ to kan latara ibasun ọran naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo sọ eyi di mimọ nigba ti wọn ṣafihan Robbinson, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, to pade ọmọge kan ti ko ju ogun ọdun lọ, lọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, lagbegbe OPIC, Agbara, nipinlẹ Ogun.

O lo agbara ọkunrin fọmọbinrin naa, o gbe e wọnu igbo, o ba a laṣepọ pẹlu tulaasi, o si tun waa fun un lọrun lẹyin eyi.

Ko tan sibẹ, niṣe lo tun gbe ọmọ naa ju si koto tawọn ọlọpaa sọ pe o jin ni iwọn ẹsẹ bata mẹwaa, o si ba tiẹ lọ.

Ọlọrun to ni ọmọbinrin naa ko ni i ku lo da ẹmi rẹ pada, to fi n pariwo lẹyin to ji ninu koto naa, to fi di pe awọn eeyan ṣaanu rẹ, ti wọn gbe e jade. Latọjọ naa lọmọbinrin yii ti wa ni ‘National Orthopaedic Hospital’, Igbobi, l’Ekoo.

Kọmandi ọlọpaa fi to ALAROYE leti pe ayẹwo awọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe eegun ẹyin rẹ (spinal cord) ti kan. Wọn ni ati dide rin ọmọge naa di ọwọ Ọlọrun Ọba ni.

Loootọ ni wọn ri Robbinson mu lọjọ kẹta iṣẹlẹ naa, to si ti wa lahaamọ latigba naa titi dasiko yii, ṣugbọn bi oju apa yoo ṣe jọ oju ara fọmọ to ba laye jẹ naa ni ko ye ẹnikan.

Ẹsun meji ni awọn ọlọpaa sọ pe awọn kọ silẹ fun un, ifipabanilopọ ati igbiyanju lati paayan, ti mejeeji jẹ ẹsun to lagbara gidi labẹ ofin.

Leave a Reply