Obinrin ti wọn lo bimọ fun ọga banki ni:Emi kọ ni mo pa ọkọ mi o

Dada Ajikanje

Obinrin ti wọn fẹsun kan pe o n ba ọga rẹ ni ajọṣepọ, ti wọn ni ọkọ rẹ kọ lo ni awọn ọmọ meji ti wọn bi, Moyọ Thomas naa ti jade sọrọ o. Obinrin yii ni oun kọ loun pa ọkọ oun o, oun lo si ni awọn ọmọ meji ti oun bi naa.

Alaye to ṣe ni pe titi di ọla, oun ko ni baba meji fun awọn ọmọ oun, afi Oloogbe Tunde Thomas.

O ni, “O ṣe pataki lati sọrọ nibi ta a de yii nipa oriṣiiriiṣii ohun tawọn eeyan n sọ nipa mi lori ẹrọ ayelujara latigba diẹ sẹyin. Ṣaaju asiko yii ni mo ti kọkọ pinnu pe mi o ni i sọ ohunkohun, ohun to si fa a ni pe, mi o ni i fẹ ohun to maa ba mi lọkan jẹ nipa iranti ohun rere ti mo ṣi ni lọkan nipa Oloogbe Tunde.

“Ko ni i wu mi ki awọn eeyan maa darukọ Tunde si ohun to le ba a lorukọ jẹ. Ẹni ti a n sọ yii ti ku ni ọjọ kẹrindinogun, oṣu kejila, ọdun to kọja. Ohun to si dara ju fun un ni ki ọkunrin yii lọọ sinmi jẹẹjẹ, dipo ariwo orukọ ẹ tawọn eeyan n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara.

“Bakan naa ni mi o ni i fẹẹ maa ri irikurii nipa ẹni yii, ati pe ki i ṣe ohun to dara fun awọn ọmọ ti mo bi fun un atawọn eeyan ti wọn sun mọ ọn paapaa.

“Gegẹ bi a ṣe mọ pe ko si igbeyawo to pe, emi ati Tunde naa ni iṣoro tiwa, bẹẹ lawọn ọlọpaa paapaa ti ba wa da si i ri. Ṣugbọn awọn ohun to dara ni mo fẹẹ maa fi ranti ẹ, nitori ko sẹni to mọ pato ohun to ṣẹlẹ laarin wa, ọrọ lọkọ-laya ni, ohun ti a ba si sọ sita lawọn eeyan maa mọ. Bẹẹ lọrọ awọn agba to sọ pe, kaluku lo mọ ibi ti bata ti n ta oun lẹsẹ. Ko sigba kan ri ti mo ro aburu ro o, bẹe lo jẹ pe iyalẹnu nla ni ọrọ iku ẹ ṣi n jẹ fun emi paapaa, bo ṣe n ya ọpọ eeyan lẹnu.”

Obinrin yii fi kun un pe ko sigba kan ti oun sọ fun ọkunrin yii pe oun kọ lo ni awọn ọmọ mejeeji ti oun bi fun un.

O ni, “Emi o mọ ibi ti awọn eeyan ti gbọ isọkusọ ti wọn n gbe kiri pe mo pe e jokoo lati sọ fun un pe oun kọ lo ni awọn ọmọ. Titi dọla lawọn ọmọ yẹn ṣi n jẹ orukọ baba wọn. Ko si ẹnikẹni to le pa eeyan kan, bẹẹ lo buru jai bi awọn eeyan ṣe n fẹsun iku ẹ kan mi lai ni ẹri kan pato to fidi ẹ mulẹ lọwọ. Ohun ti mo mọ ni pe Ọlọrun nikan lo ni ikapa ẹmi gbogbo eeyan lọdọ.”

Moyọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko fẹra mọ gẹgẹ bii lọkọ-laya, sibẹ, awọn ko jẹ ki o di ojuṣe awọn lọwọ tabi ba aarin awọn jẹ nitori awọn ọmọ to wa ninu igbeyawo naa.

“Ko sigba to fẹẹ ba awọn ọmọ ẹ sọrọ ti ki i ṣe bẹẹ, titi digba to fi jade laye lo n ba awọn ọmọ yẹn sọrọ gẹge bii baba si ọmọ, bẹẹ lo jẹ ohun ibanujẹ nla fun mi bi mo ṣe n ri fọto awọn ọmọ mi lori ikanni ayelujara loriṣiriiṣii pẹlu awọn iroyin to jinna si ootọ, tawọn eeyan paapaa n sọ oriṣiriiṣii awọn ọrọ kobakungbe si mi.

“Lọkan mi, adura mi ni pe ki Ọlọrun fun awọn ẹbi ẹ atawọn ọrẹ ẹ ni oore-ọfẹ lati le fara da iṣẹlẹ bhuruku to ṣelẹ si Tunde. Gbogbo wa pata ni iku ẹ ka lara, to si dun gidigidi. Ohun ta a si nilo lasiko yii ni anfaani lati kẹdun ẹni wa to lọ, ki awọn eeyan sinmi oriṣiriiṣi nnkan buruku ti wọn n kọ kiri nipa iṣẹlẹ yii.”

Bi Moyọ ṣe sọrọ ọhun niyẹn o, ṣugbọn o jọ pe ọrọ naa ti kọja bẹẹ nitori o ti ta ba olori, bẹẹ lo ta ba ẹlẹmu paapaa. Ọga banki, Adam Nuru, ti wọn sọ pe wọn jọ n ṣe wọle-wọde nigba ti oun naa n ṣiṣẹ ni ileefowopamọ FCMB naa ti fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun.

Ni kete ti wọn ti fẹsun kan an pe oun ni Moyọ bi awọn ọmọ ẹ mejeeji fun ni banki FCMB ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ẹṣun ọhun, bakan naa ni ọkunrin yii paapaa naa ti ṣe gaafara kuro lori ipo ẹ, ti ẹlomi-in, Arabinrin Yẹmisi Ẹdun, si ti gba ipo naa gẹgẹ bii ọga agba fun banki ̀ọhun.

Adam Nuru naa ti kuro ni Naijria bayii, wọn lo lọọ sinmi, bakan naa lawọn eeyan n sọ pe ọrọ to gbọdọ lojutuu ni, nitori Tunde ko gbọdọ ronu ku bẹẹ lasan.

Ṣadeede ni ariwo nla gbalu ni nnkan bii osẹ meji sẹyin, nigba ti ẹnikan lọ sori ikanni abẹyẹfo ẹ, nibi to ti la a mọlẹ pe Oloogbe Tunde Thomas to ti ṣiṣẹ ni banki Oceanic tẹlẹ ri, to jade laye ninu oṣu kejila, ọdun to kọja, ko ṣadeede ku o, ọdọ iyawo ẹ tẹlẹ, Moyọ Thomas, ni ki wọn wa iku ẹ si.

Lori ikanni ọhun lẹni to sọrọ yii ti fidi ẹ mulẹ pe, ọmọ mejeeji ti Moyọ bi fun Tunde, to sọ pe oun kọ lo ni wọn lo da wahala silẹ, ninu eyi ti arun rọpa-rọse ti kọkọ kọ lu u lọdun 2017, nigba to si di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, lojiji ni ọkan ọkunrin naa daṣẹ silẹ, n lo ba dagbere faye.

Ni kete ti wọn ti sin ọkunrin yii tan ni awuyewuye ti bẹ silẹ, ọrọ ọhun si ti ko ọga banki FCMB, Ọgbẹni Adam Nuru, si wahala paapaaa lori pe oun ati Moyọ jọ n ṣe wọle-wọde, ati pe oun gan-an ni wọn sọ pe Moyọ lo ni awọn ọmọ ọhun.

Bi wọn ṣe n gbe ọrọ ọhun kiri niyẹn o, ti ẹnikẹni ko si gbọ nnkan kan lati ẹnu Moyọ, to ti n gbe ni America pẹlu awọn ọmọ ẹ mejeeji bayii.

Leave a Reply