Obinrin to ba ṣẹṣẹ bimo ni ipinlẹ Ọyọ, oṣu mẹfa ni yoo fi sinmi nile

Aderounmu Kazeem

Idẹra ti de bayii fawọn obinrin ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọyọ, bi Gomina Ṣeyi Makinde ṣe fọwọ si i ki awọn to ba ṣẹṣẹ bimọ ninu wọn maa fi oṣu mẹfa sinmi.

Tusidee, ọjọ Iṣẹgun, to kọja yii ni Enjinnia Ṣeyi Makinde fọwọ si ofin tuntun yii lasiko to ṣepade pẹlu awọn igbimọ rẹ nile ijọba ni Agodi, niluu Ibadan.

Ọkan lara awọn Kọmiṣanna, rẹ to ba awọn oniroyin sọrọ, Ọjogbọn David Ṣangodoyin, sọ pe ijọba gbe igbesẹ naa lati fun awọn alabiyamọ laarin awọn oṣiṣẹ ẹ lanfaani lati tọju ọmọ ti wọn ba ṣẹṣẹ bi ọhun daadaa ni.

Bakan naa lo sọ pe anfaani wa lati gba aaye isinmi ọhun lẹẹmẹrin lasiko igba ti awọn obinrin ba fi wa lẹnu iṣẹ.

Ṣangodoyin, fi kun un pe, ti o ba ti ku ọsẹ mẹrin ti alaboyun yoo bimọ lo ti lanfaani lati bẹrẹ isinmi ọhun, titi ti oṣu mẹfa ọhun yoo fi pe lẹyin to ba bimọ tan, to si ti tọju ọmọ ẹ daadaa.

Ṣaaju asiko yii, oṣu mẹrin pere ni ijọba fun awọn obinrin lẹnu iṣẹ lati maa lo fi sinmi lasiko ti wọn ba ṣẹṣẹ bimọ.

Ijọba tun sọ pe ti wọn ba ti wọle pada lẹyin sinimi oloṣu mẹfa ọhun, aago mẹrin ti awọn oṣiṣẹ yooku n lọ sile, lawọn naa yoo maa lọ sile, ko ni i si aaye fifi ibiiṣẹ silẹ laago meji ọsan bii tẹlẹ mọ.

 

Leave a Reply