Obinrin to ba bimọ nipinlẹ Ọyọ, oṣu mẹfa ni yoo maa lo nile, ijọba ti fẹẹ fọwọ si i

Bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ba fi le mu ileri rẹ ṣẹ, a jẹ pe awọn to ba ṣẹṣẹ bimọ nipinlẹ naa ti bọ saye niyẹn, nitori pe oṣu mẹfa ni awọn iyalọmọ naa yoo maa lo nile ki wọn too pada sẹnu iṣẹ.

Kọmiṣanna fun ọrọ awọn obinrin nipinle Ọyọ, Arabinrin Faosat Sanni, lo sọrọ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nibi ipade ọlọjọ meji kan ti ẹgbẹ awọn akọroyin obinrin (NAWOJ), ẹka ti ipinlẹ Ọyọ, ṣe ni Aderọgba Hall, ni Gbongan awọn Akọroyin to wa ni Iyaganku, niluu Ibadan, eyi ti akori rẹ jẹ ‘Ẹ daabo bo awọn Iyalọmọ.’

Sanni ni afikun asiko igbele awọn obinrin lẹyin ti wọn ba bimọ yii ṣe pataki nitori yoo fun wọn ni anfaani lati tọju ikoko naa daadaa, awọn paapaa yoo si le tọju ara wọn. O ni gbogbo atilẹyin to yẹ ni ijọba Ṣeyi Makinde n fun awọn obinrin nipinlẹ naa lati ṣe amojuto to daa fun wọn.

O fi kun un pe latilẹ ni ijọba ti n daabo bo awọn obinrin ati ọmọ wẹwẹ, ti wọn n kọ wọn lẹkọọ, ti wọn si n ṣe iranlọwọ lọlọkan-o-jọkan fun wọn. Bẹẹ lo ni awọn n mojuto wọn lati ri i pe ẹnikẹni ko lo awọn obinrin ati ọmọde nilokulo, awọn si n pese iranlọwọ owo fun awọn ti wọn nilo rẹ ninu wọn.

Bakan naa ni Alaga to n ri si ọrọ awọn obinrin ati idagbasoke awujọ nileegbimọ aṣofin, Ọnarebu Wumi Ọladeji, sọ pe ipa kekere kọ ni awọn aṣofin n ko lori itọju awọn ọmọde atawọn obinrin. O ni gbogbo eto awọn lo fi ti awọn obinrin atawọn ọmọde ṣe lati fun wọn ni itọju to yẹ. Bakan naa lo ni oriṣiiriṣii ofin lawọn ti ṣe lati mojuto ọrọ awọn ọmọde ati obinrin. Ati pe ileegbimọ aṣofin Ọyọ lo kọkọ sọ ofin to n ja fun ẹtọ awọn ọmọde di ti ipinlẹ lọdun 2006.

Sanni ni oriṣiiriṣii ofin to wa fun didaabo bo awọn obinrin lawọn n ṣiṣẹ le lori nileegbimọ aṣofin lọwọ.

Kọmiṣanna fun eto Iroyin Aṣa ati Igbafẹ nipinlẹ Ọyọ, Dokita Wasiu Ọlatubọsun, to ṣide eto naa sọ pe gbogbo agbara ni ipinlẹ Ọyọ n ṣa lati din iya to n jẹ awọn obinrin ku, ati lati jẹ ki wọn gbe igbesi aye to rọrun.

O waa rọ awọn iyalọmọ lati kun fun adura, ki wọn si ṣatilẹyin to yẹ fun awọn ọkọ wọn bi wọn ṣe n lakaka lati goke agba lẹnu iṣẹ ti wọn yan laayo.

Leave a Reply