Obinrin yii bẹ ọkọ ẹ lori nitori ẹsun agbere

Adefunkẹ Adebiyi

Rachel Tetteh lobinrin to kawọ gbera yii n jẹ, lẹyin to bẹ ọkọ ẹ lori tan nitori ẹsun agbere ti wọn jọ fi n kan ara wọn lawọn ọlọpaa mu un, iyẹn lọjọ Aiku,  Sannde, ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa yii.

Orilẹ-ede Ghana nisẹlẹ yii ti ṣẹ, ni Tei Glover, nitosi oko Akyem Bosuso, Ila-Oorun Ghana.

Gẹgẹ bawọn ẹka iroyin agbegbe naa to fiṣẹlẹ yii sita ṣe ṣalaye, wọn ni ọrọ ẹsun agbere lo da wahala silẹ, pe ọkọ Rachel torukọ ẹ n jẹ Lartey Daniel, ẹni ọdun marundinlogoji (35) pẹlu iyawo rẹ jọ n fẹsun iṣekuṣe kan ara wọn ni. Wọn bi ọkọ ṣe n sọ pe iyawo n rin irinkurin niyawo naa n naka sọkọ rẹ pe oniranu kan ni.

Ko pẹ lọkọ kọri sọna oko, nigba naa ni Rachel, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) yọ tẹle e lẹyin, iyẹn ko si mọ pe obinrin naa n tẹle oun lẹyin pẹlu ada to mu buruku lọwọ.

Bi Rachel ṣe de ẹyin ọkọ ẹ lo bu u lada lọrun latẹyin, peregede lori ọkọ yii bọ lọrun rẹ, ti agbara ẹjẹ gba oju ọna oko naa yika, ti Lartey Daniel si japoro titi to fi dakẹ.

Gbunduku ara rẹ wa nilẹ, ori wa ni oju ọna oko naa nibẹ bi wọn ṣe wi, iran buruku gbaa ni.

Ẹsẹkẹsẹ lawọn ara oko ti lọọ sọ fọlọpaa, ko si pẹ rara ti wọn fi yọju sibi iṣẹlẹ naa.

Alukoro ọlọpaa ẹkun yii, DSP Ebenezer Tetteh, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣalaye pe awọn ba oku ọkọ-iyawo naa ti ko ni ori, aṣọ funfun lo wọ le ṣokoto alawọ eeru.

O fi kun un pe aala oko naa lawọn ti ri ori ẹ nibi ti iyawo rẹ ge e si, awọn si tọ ẹjẹ rẹ debi ti ori naa wa ni, lawọn ba gbe e lọ sile itọju oku, ko too di pe wọn yoo ṣe ayẹwo si i.

Ọlọpaa naa sọ pe awọn ri Rachel to ge ọkọ ẹ lori mu, ọdọ awọn lo wa lati ọjọ Sannde naa to n ran awọn lọwọ lori iwadii awọn.

Leave a Reply