Obinrin yii fi mọto paayan n’Ikẹja, lo ba lọọ tẹ oku ẹ sẹgbẹẹ titi loru ni Mowe

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣafihan obinrin awakọ kan, Abilekọ Taiwo Alaka, ti wọn fẹsun kan pe o fi mọto pa obinrin ẹgbẹ ẹ kan, kaka ko lọọ jẹwọ fawọn agbofinro, niṣe lo lọọ dọgbọn tẹ oloogbe naa ṣẹgbẹẹ titi, loun ba sa lọ, titi tọwọ fi tẹ ẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, lo ṣafihan afurasi ọdaran naa lọfiisi rẹ n’Ikẹja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Odumosu ni agbegbe Ikẹja niṣẹlẹ naa ti waye lọsẹ to kọja lọhun-un, wọn lobinrin to kagbako iku ojiji naa fẹẹ sọda titi ni, to fi ṣe kongẹ ọkọ ayọkẹlẹ ti Taiwo n wa bọ, o si gba a gidi.

Oju-ẹsẹ ni wọn lawọn ero ti pe le wọn lori, wọn si fipa mu obinrin naa lati ṣaaju ẹni to kọ lu, bẹẹ ni wọn gbe oloogbe naa de oṣibitu aladaani kan to wa nitosi, ṣugbọn gbogbo igbiyanju awọn oniṣegun lati doola ẹmi oloogbe naa lo ja si pabo.

Taiwo ni “Loootọ niṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn mi o mọ-ọn-mọ. Mo gbiyanju lati ṣaajo ologbe naa, ọsibitu lo ku si. Loootọ ni Dokita sọ fun mi nigba to n yọnda oku naa pe ki n tete lọọ sọ ohun to ṣẹlẹ yii fawọn ọlọpaa, ṣugbọn ẹru ba mi, ati pe ọrẹ mi obinrin kan to wa pẹlu mi lọjọ naa lo kọ mi pe ki n ma tiẹ gbero lati sọ ohunkohun rara, emi ati ẹ naa la si jọ lọọ tẹ oku naa sẹgbẹẹ titi loru, oju ọna marosẹ Eko s’Ibadan la tẹ ẹ si.

Wọn ni ma ṣe e loogun ma mọ ọn, ẹnikan to fura si wọn, to si ri ohun to n ṣẹlẹ lọjọ naa lo ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo. Odumosu ni kia lawọn ọmọọṣẹ oun ti debẹ, wọn ba oku naa to na gbalaja sẹgbẹẹ titi, wọn o ri awakọ dirẹba naa, ni wọn ba bẹrẹ si i tọpasẹ ẹ, wọn si dọdẹ ẹ titi tọwọ fi ba a.

Kọmiṣanna ni awọn ti lọọ tọju oku naa si mọṣuari, awọn si ti ṣe ayẹwo to yẹ nipa ẹ. O lawọn ọlọpaa otẹlẹmuyẹ ti n ṣiṣẹ lori bi wọn ṣe maa ri obinrin keji to lo gba oun nimọran aidaa naa mu, awọn yoo pari iwadii to n lọ lọwo lori ẹsun yii.

Ṣugbọn boya wọn ri ẹni keji ẹ mu tabi bẹẹ kọ, Odumosu ni gbara tiṣẹ iwadii ba ti pari lobinrin afurasi ọdaran yii maa balẹ sile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply