Obinrin yii fi ọbẹ gbigbona da ọgbẹ sẹyin ọmọọdọ ẹ nitori ọgọrun-un Naira

Faith Adebọla, Eko
Gbogbo ọna nileeṣẹ ọlọpaa Eko ati awọn ọtẹlẹmuyẹ n ṣan bayii lati ri obinrin kan, Evidence Eseogbene, fun iwa ika ati ọdaju to hu, niṣe lo fi ata ati ọbẹ gbigbona dapaa sẹyin Victory Oghenovo, ọmọọdun mẹwaa to n ṣọmọọdọ lọdọ ẹ, latari pe iyẹn fi ọgọrun-un Naira jẹun lara owo ọja to pa nigba tebi n pa a.
Ba a ṣe gbọ, Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, niṣẹlẹ naa waye. Ọdọ Evidence lọmọọdọ naa n gbe niluu Lẹkki, oun lo si maa n ba ọga rẹ yii duro sidii okoowo POS tobinrin naa n ṣe ni Adeba, laduugbo Lakọwe, ni Lẹkki.
Wọn ni l’Ọjọbo, Tọsidee, ọmọbinrin yii nikan lo wa nidii POS lataarọ ṣulẹ, ọga rẹ ko wa lọjọ naa, ko si gbe ounjẹ ti ọmọọdọ yii yoo jẹ ranṣẹ. Ounjẹ to ti jẹ nile laaarọ lo wa nikun ẹ.
Nigba tebi n pa ọmọ naa lọsan-an, ti ko si ri ọga rẹ lo ba mu ọgọrun-un Naira lara owo ọja to pa, o fi ra pọfupọọfu jẹ, o tun mu Zobo si i. Eyi lo fa wahala nigba to dele.
Gẹgẹ bọmọ naa ṣe fẹnu ara ẹ sọ, o niṣe lọga oun bẹrẹ si i lu oun nilukulu nigba toun ṣiro owo ọja fun un, ti owo naa si din ọgọrun-un Naira, oun si sọ fun un pe ounjẹ loun fi owo to din naa ra.
Lẹyin ti Evidence lu ọmọ yii ti ko tẹ ẹ lọrun, wọn lo fẹ ata gigun soju ọmọ naa, igba ti ọmọ naa figbe ta ti ko riran, lo ba fi ọbẹ gigbona yọ lori gaasi idana to fi i si, o si fi ya batani sẹyin ọmọọdọ ọhun, bẹẹ lọmọ naa jẹrora gidi.
Lọjọ keji tọmọ naa de ibiiṣẹ POS wọn ni ọkan lara awọn kọsitọma to fẹẹ gba owo lẹnu ẹrọ ṣakiyesi pe Victory ko le rin daadaa, wọn lẹẹmeji lo ṣubu lori aga to jokoo si, igba tawọn eeyan si fẹẹ gbe e dide laṣiiri tu bi wọn ṣe ri ọgbẹ yankan yankan to wa lẹyin ẹ, lọmọ naa ba ṣalaye ohun tọgaa ẹ foju ẹ ri fun wọn.
Ibinu ọrọ yii lo mu kawọn aladuugbo atawọn kọsitọma naa pe ileeṣẹ ajafẹtọọ awọn ọmọde ti ki i ṣe tijọba kan, Advocate for Children and Vulnerable People’s Network (ACVPN), lori aago.
Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ yii ni wọn waa mu ọmọkunrin yii, ti wọn si lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ẹlẹmọrọ, lagbegbe Lẹkki, nigba ti wọn si fi maa de ile wọn, o jọ pe olobo ti ta Evidence, ọga rẹ, tori wọn ko ri i, ko si yọju sile latigba naa, wọn niṣe lo fara ṣoko.
Wọn tun ri apa mi-in lara ọmọọdọ yii, oju ọgbẹ to ti jinna ni, ọmọ naa si ṣalaye pe ọga oun lo pe Alaaja kan ti wọn jọ n gbe adugbo pe ko b’oun fiya jẹ oun lọjọ kan toun ṣẹ ọga naa, ni Alaaja ọhun ba dọgbẹ si i lara.
Awọn ọlọpaa ti mu Alaaja yii lọ sahaamọ wọn, ṣugbọn a gbọ pe wọn ti fi i silẹ nitori ipo abara meji to wa.
Wọn ṣi n wa Evidence titi di ba a ṣe n sọ yii.

Leave a Reply