Obinrin yii ji ọmọ gbe ni Nasarawa, lo ba gbe e sa lọ si Benue

Niṣe ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, tẹkọ leti lọ si ipinlẹ Benue, lati mu obinrin ti ẹ n wo fọto rẹ pẹlu ọmọ lọwọ yii. Idi ni pe niṣe lobinrin torukọ ẹ n jẹ Sewuese Humba naa sa kuro ni Nasarawa to n gbe lẹyin to ji ọmọkunrin naa lọjọ kẹjọ, oṣu yii, o sa lọ si Benue pẹlu ọmọ ọlọmọ.

Iya ọmọ naa gangan, Queen Moses, to n gbe ni Gidan Zakara, nijọba ibilẹ Karu, nipinlẹ Nasarawa, lo sunkun lọ si teṣan lọjọ naa, pe ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ, ti oun n sun oorun aarọ lọwọ pẹlu ọmọ oun to jẹ ọmọ oṣu mẹrin, ni Sewuse wọle, to si ji ọmọ naa gbe lọ lẹgbẹẹ oun. O ni nigba toun ji loun ko ri ọmọ mọ, kawọn ọlọpaa ṣaanu oun.

N lawọn eeyan ba bẹrẹ si i wa Sewuse, awọn ọlọpaa naa n tọpinpin, afi bi wọn ṣe gbọ pe Benue lo sa lọ.Wọn wa a debẹ, wọn si ri i pẹlu ọmọ ọlọmọ to ji gbe naa, bi wọn ṣe mu un niyẹn.

Awọn ọlọpaa gba ọmọ naa lọwọ ẹ, wọn gbe e lọ sọsibitu fun itọju, wọn si mu ajọmọgbe naa pada si Nasarawa, wọn sọ ọ sẹyin gbaga.

Leave a Reply