Obinrin yii ji ọmọ ọlọmọ meji gbe ni Ṣiun, Italy lo fẹẹ ta wọn si kọwọ too tẹ ẹ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Comfort Innocent lorukọ obinrin ti ẹ n wo fọto rẹ yii, iṣẹ awọn to n ji ọmọ ọlọmọ gbe ti wọn yoo si ta wọn sorilẹ-ede Italy lo n ṣe. Ohun to ṣe ni Ṣiun, nipinlẹ Ogun, ree tọwọ fi ba a lọjọ kejilelogun, oṣu kejila yii.

Awọn ọmọbinrin meji tọjọ ori wọn jẹ mẹẹẹdogun ati mẹrindinlogun (15,16) ni Comfort ji gbe tọwọ fi ba a, orukọ awọn ọmọ naa ni Blessing Aduratọla, ọmọ ọdun mẹẹẹdogun, ati Hasisat Fasasi toun jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun.

Awọn iya awọn ọmọ naa lo lọọ fi to awọn ọlọpaa leti pe Comfort ti gbe awọn ọmọ awọn lọ o, awọn ko ri i debi tawọn yoo ri awọn ọmọde meji naa. Bẹẹ, aladuugbo jọ lawọn ni Ṣiun, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode tawọn n gbe. Wọn ni ogbologboo ajọmọgbe ni Comfort laduugbo, o si ti fẹẹ ko awọn ọmọ meji naa sọda si orilẹ-ede Italy ti wọn yoo ti maa fi wọn ṣiṣẹ aṣẹwo.

Kia ni teṣan ọlọpaa Owode-Ẹgba ti wọn mu ẹjọ naa lọ bẹrẹ iṣẹ lori ẹ, wọn si ri Comfort mu lẹyin iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn ṣe.

Obinrin ẹni ọdun marundinlogoji (35) naa jẹwọ fun wọn pe iṣẹ ajọmọgbe loun n ṣe loootọ. O ni ọkọ oun wa lorilẹ-ede Italy, boun ba ji awọn ọmọdebinrin gbe nibi, oun yoo fi wọn ṣọwọ sọkọ oun lọhun-un, ṣugbọn orilẹ-ede Libya ni wọn yoo gba wọ Italy tọkọ oun wa, bi wọn ba si ti de ọhun ni wọn yoo bẹrẹ iṣẹ aṣẹwo tawọn tori ẹ ji wọn gbe ni Naijiria nibi.

Njẹ nibo lawọn ọmọ meji yii wa bayii, Comfort loun ti fi wọn ranṣẹ si Kaduna, ibẹ ni wọn yoo gba de Libya, ki wọn too pari ẹ si Italo ti wọn yoo ti di aṣẹwo pọnbele.

 

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun to fi iṣẹlẹ naa to ALAROYE leti, ṣalaye pe awọn ti gbe obinrin yii lọ sẹka to n ri si ijinigbe ati lilo ọmọde nilokulo, gẹgẹ bii aṣẹ CP Edward Ajogun.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun naa waa kilọ fawọn obi ti wọn ni ọmọbinrin pe ki wọn mojuto wọn daadaa, ki wọn ma fi ọmọ tafala debi ti ọwọ iru awọn Comfort yii yoo maa tẹ wọn, nitori ọmọ ti wọn ba sọ loko si Italy yoo rihun royin lọhun-un, awọn eeyan rẹ ni Naijiria si le ma foju kan an mọ laye.

Wọn ti ri Blessing ati Hasisat gba pada gẹgẹ bi Oyeyẹmi ṣe wi.

Leave a Reply