Ọdaju l’Ọpẹyẹmi yii o, o si yinbọn pa Ṣẹgun n’Ileefẹ

Florence Babaṣọla

 

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ ti ju ọmọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Bamigboye Ọpẹyẹmi, sẹwọn lori ẹsun ipaniyan.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun yii, la gbọ pe olujẹjọ yinbọn pa Ṣẹgun Awotunde laago mẹta aabọ ọsan labule Oke-Ọra, nitosi ilu Ileefẹ.

Inspẹkitọ Elijan Adeṣina ṣalaye pe yatọ si Ṣẹgun ti olujẹjọ yinbọn pa lọjọ yii, ori lo tun ko awọn meji mi-in; Ọpẹyẹmi Rabiu ati Adesọji Yinka, yọ lọjọ naa pẹlu ibọn to yin si wọn, to si jẹ pe ileewosan lawọn eeyan sare gbe wọn lọ.

Adeṣina ṣalaye pe iṣẹlẹ naa da wahala nla silẹ ninu abule Oke-Ọra, lọjọ naa, to si jẹ pe lẹyin ọpọlọpọ wakati ni awọn ti wọn ti sa lọ to pada sibẹ.

O ni iwa yii lodi, bẹẹ ni ijiya wa fun un ninu abala ọtalelugba o din mọkanla (249), okoolelọọọdunrun-un o din ẹyọ kan (319) ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (516) ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tijọba ipinlẹ Ọṣun n lo.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ A. I. Oyebadejọ sọ pe ile-ẹjọ Majisreeti ko lagbara lati gbọ ẹjọ ipaniyan, nitori naa, o ni ki agbefọba mu ẹda iwe ipẹjọ naa lọ si ẹka to n gba ile-ẹjọ nimọran lori ọrọ awọn araalu nileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun.

O waa paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Ọpẹyẹmi pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ titi di ọjọ kẹta, oṣu karun-un, tigbẹẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.

 

Leave a Reply