‘Ọdọ iya iyawo mi ni mo maa n tọju ibọn ta a fi n ṣiṣẹ ijinigbe ati ole jija si’

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Johnson Apotire, Jimọh Dele, ti wọn tun maa n pe ni Dele Petim, Ayẹni Blessing ati Fẹmi Adewale, ti   wọn jẹ ọmọ bibi ilu Agbado-Ekiti, nijoba ibilẹ Gbọyin, nipinlẹ Ekiti, lọwọ palaba wọn ṣegi l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii.

Awọn mẹrin yii ni awọn ọlọpaa sọ pe wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe gbe baba oniṣowo epo bẹntiro kan, Alhaji Suleiman Akinbami, gbe niluu Ado-Ekiti ninu oṣu kẹta ọdun yii, ati awọn iṣẹlẹ ijinigbe miiran to ti n waye nipinlẹ naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, aipẹ yii ni ajọ ọlọpaa, nipinlẹ Ekiti ṣe kede pe awọn ṣetan lati san miliọnu marun-un fun ẹnikẹni to ba mọ bi awọn ṣe le ri awọn ọdaran wọnyi.
Meji lara awọn janduku yii, Johnson Apotire ati Fẹmi Pẹtim, ni awọn ọlọpaa sọ pe ọwọ awọn tẹ niluu Ilọrin, ti wọn si jẹwọ pe iṣẹ ajinigbe lawọn yan laayo, ati pe awọn maa n ṣe bii Fulani ni ti awọn ba ti ji eeyan gbe, nitori pe wọn jọ Fulani gidi gan-an ni.
Awọn meji to ku lọwọ awọn agbofinro tẹ niluu kan ti wọn n pe ni Erùkú, to wa lẹgbẹẹ Ilọrin, ti awọn naa si jẹwọ pe ki awọn too bẹrẹ iṣẹ ajinigbe, iṣẹ ki wọn ja ṣọọbu ati ile fifọ ni awọn n ṣe tẹlẹ.
Wọn sọ pe nigba miiran, awọn maa n fi ibọn gba ọkada, ati pe awọn ti gba ọkada bii mejila ninu ọdun yii. Bakan naa ni wọn ni awọn ti ja ṣọọbu bii mẹwaa ninu ọdun yii, ki ọwọ too tẹ awọn.
Ọkan lara awọn ọdaran yii, Dele Petim, sọ pe ibọn mẹrin ti awọn ọlọpaa gba lọwọ oun yii ni oun maa n ko pamọ si ile iya iyawo oun ni Ado-Ekiti lẹyin ti oun ba ti ṣe ọṣẹ́ tan.

Bakan naa ni wọn darukọ Alhaji Ahmed Adebayọ to wa niluu Ilọrin pe oun lo maa n ba awọn ta ọja ti awọn ba ti ji ko, ti awọn ọlọpaa si sọ pe awọn yoo ṣe afihan rẹ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ naa.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe meji lara awọn ọdaran naa, Samuel Ebira ati Dayọ Igwe ti awọn ọlọpaa ṣi n wa, iṣẹ tiwọn ni ki wọn wa ẹni ti wọn yoo ji gbe silẹ. O fi kun un pe ọdaran yii gan-an lo fi Oloogbe Abiodun Ayẹni ti wọn ji gbe loju ọna Ikọgosi si Ẹrinjiyan-Ekiti, to si fo jade lati inu ọkọ awọn ajinigbe yii lojiji, eleyii to pada ja si iku fun un nile-iwosan.
Bakan naa ni alukoro awọn ọlọpa yii tun sọ pe ọwọ awọn ti tun tẹ ọkunrin to n ṣiṣẹ ọlọpaa tẹlẹ, Ayọ Samuel, ẹni ọdun metalelọgọta, to jẹwọ pe oun ti kopa ninu iṣẹlẹ ijinigbe to to bii meje ni oriṣiiriṣii agbegbe nipinlẹ Ekiti. O fi kun un pe gbogbo awọn wọnyi ni wọn yoo ko lọ si ile-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ wọn.
Lara awọn ẹru ti wọn gba lọwọ wọn ni, miliọnu meji Naira, Irun ti awọn obinrin maa n ran mọ ori, aṣọ ọlọpaa ati ti ṣọja, ibọn ilewọ bii mẹrin ati ọkọ ayọkẹlẹ kan.

Leave a Reply