Ọdọ Sikiru ni Sakiru ti kọṣẹ ole jija, lo ba loun ti ji foonu bii ojilerugba (240)

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Afi bii ikun loko ẹpa, bẹẹ lọrọ ole jija ati foonu jijigbe ṣe ri fun afurasi ọdaran kan, Ayọmide Sikiru, tọwọ awọn ọlọpaa ba yii. O ni aropọ foonu toun ti ji ti to ojilerugba (240).

Ba a ṣe gbọ, ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa (Rapid Response Squard, RRS) ni wọn mu ọkunrin ẹni ọdun metadinlọgbọn yii ni aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Mọnde, wọn lo ṣẹṣẹ ja baagi mama agbalagba kan gba tan ni, bọọsi ni mama naa fẹẹ wọ ni Ojodu-Berger, ti wọn fi fa baagi yọ mọ ọn lapa.

Wọn ni bo ṣe yọ baagi tan, o yọ foonu inu baagi ọhun, o sọ baagi silẹ, lai mọ pe ero kan to fẹẹ wọle ṣakiyesi ohun to n ṣẹlẹ. Ero yii lo ṣọ fun un pe ko da foonu to ji yẹn pada, ṣugbọn Sikiru sẹ kanlẹ pe oun ko ji foonu kan, bẹẹ ni ko si gba ki wọn yẹ apo ẹ wo, lawọn eeyan ba gan-an lapa, wọn lọọ fẹjọ ẹ sun awọn ọlọpaa RRS to wa labẹ igi kan n’Iyana Oworo.

Ko ri agidi ṣe fawọn ọlọpaa, ara ẹ ti balẹ nigba to ri wọn, ni wọn ba yẹ ara ẹ wo, wọn si ri foonu mama agbalagba ọhun lapo ẹ, Tecno Camon 12 kan bayii ni.

Yatọ si Tecno Camon 12 yii, wọn tun ba iPhone 7 mi-in, nigba ti wọn si yẹ foonu ọhun wo, wọn ri i pe oun kọ lo ni in, ni wọn ba kan si ẹni to ni in lori aago awọn ọrẹ torukọ wọn wa ninu foonu ọhun, oju-ẹsẹ niyẹn si ba wọn nibẹ, o ni wọn yọ foonu naa mọ oun lara ni lowurọ ọjọ naa.

Awọn ọlọpaa wọ Sikiru de teṣan wọn, ibẹ lo ti jẹwọ pe ọsẹ meji loun fi kọṣẹ oriṣiiriṣii ọna teeyan fi le jale, o ni Ṣakiru kan lo fọwọ kinni ọhun han oun.

Wọn lo tun jẹwọ pe ọdun kan atoṣu meji loun ti fi jale, ọjọ mẹta pere loun fi n ṣiṣẹ ole jija lọsẹ, opin ọsẹ lọwọ oun maa n dẹ ju, aropọ foonu toun si ti ri ko fi bẹẹ pọ, ko ju ojilerugba lọ, boun ṣe n ri i loun n ta a, toun si n fowo ẹ ṣaye ni toun.

Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, lawọn ti fi ṣọwọ si Panti, ni Yaba, ibẹ lọrọ ẹ maa gba dele-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply