Ọdọmọkunrin mẹtala dero atimọle EFCC, wọn ni won n lu awọn eeyan ni jibiti

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ọdọmọkunrin mẹtala lajọ to n gbogun ti magomago owo ati iwa jibiti nilẹ yii, EFCC, ẹkun Ibadan, da satimọle wọn lọjọ kan ṣoṣo.

Lode ariya kan lawọn EFCC ti mu gbogbo wọn lẹyin ti wọn ti fura sí wọn pe jibiti lilu lori ẹrọ ayélujára ni wọn sọ di iṣẹ aje ní tiwọn.

Gẹgẹ bí ẹka tó n gbẹnusọ fún ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ṣe fìdí ẹ mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, lọjọ Aje, Mọnde, to lọwọ tẹ awọn afurasi ọdaran yii lẹyin ti awọn eeyan kan ti ta ọfiisi awọn lolobo pe awọn ọmọ Yahoo n ba owo ninu jẹ lọwọ nileetura naa.

Orukọ awọn afurasi arufin ọhun ni Kayọde Adeoye, Ogunlẹyẹ Yẹmi, Adio Taheed, Ọlaniyi Joshua, AbdulAfeez Kẹhinde ati Bakare Ọmọlayọ, Adesuntọla Adebayo, Ridwan Gbolahan, Abdulfatai Waliu, Ọlayiwọla Ọlamilekan, Raji Wasiu, Ọlawale Ibrahim ati Tajudeen Mojeed.

Ọkọ ayọkẹlẹ mẹrin ọtọọtọ ti owo ọkọọkan wọn kò mọ ni miliọnu kekere naira ni wọn ba nile wọn.

Laipẹ jọjọ lajọ EFCC yoo foju wọn ba ile-ẹjọ fun riru ofin orile-ede yii to ṣe jibiti lilu, paapaa lori ẹrọ ayélujára leewọ

Leave a Reply