Odumosu kilọ fawọn ọmọọṣẹ ẹ: Ẹ yee ko ipaya ba araalu o

Faith Adebọla, Eko

 Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, ti laago ikilọ setiigbọ awọn ọmọọṣẹ rẹ pe wọn o gbọdọ jẹ kẹnikẹni lo wọn lati dana ijangbọn silẹ nibikibi, ki wọn si yago patapata fun kiko jinnijinni ati ipaya ba awọn olugbe Eko.

Odumosu sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, lasiko to n ba awọn ẹṣọ ti wọn ṣẹṣẹ yan si ikọ patiroolu ati tawọn alaabo ara-ẹni nipinlẹ Eko sọrọ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa Eko, eyi to wa n’Ikẹja.

Kọmiṣanna naa sọ pe iṣẹ ọba tijọba yan fun wọn, paapaa awọn ọlọpaa ti wọn yan lati maa tẹle awọn eeyan pataki pataki lawujọ, ni lati pese aabo, ki i ṣe ki wọn lọọ maa ja, tabi ki wọn gbe sẹyin awọn oloṣelu, tabi ẹgbẹ oṣelu eyikeyii.

O ṣekilọ pe ọlọpaa yoowu tọwọ ba tẹ pe o sọ ibiiṣẹ ti wọn yan an si di jẹun-jẹun, tabi to n dunkooko mọ araalu lọnakọna, maa geka abamọ jẹ ni, nigba tawọn ba fi’mu ẹ danrin.

O tun kilọ pe awọn ọlọpaa patiroolu ko laṣẹ lati ṣe afurasi ọdaran ṣikaṣika, wọn o si gbọdọ sọ ara wọn di ẹrujẹjẹ loju popo, tori awọn iwa bẹẹ n ta epo saṣọ aala ileeṣẹ ọlọpaa ni, ijọba o si ni i fojuure wo ẹni to ba ṣeru.

Ni ikadii, Odumosu rọ awọn ọlọpaa naa lati fọwọ dan-in dan-in mu ọrọ aabo ara wọn, tori mọja mọsa la a mọ akinkanju logun, o ni wọn gbọdọ maa daabo bo ara wọn funra wọn, ati araalu pẹlu.

Leave a Reply