Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, ti kede ọjọ Ẹti, Furaidee, to n bọ, iyẹn ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati fun awọn ẹlẹsin abalaye laaye lati ṣe ayẹyẹ ọdun Iṣẹṣẹ ọdun 2021.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun ọrọ ibagbepọ idile (Commissioner for Home Affairs), Alhaji Tajudeen Ọlaniyi Lawal, fi sita lorukọ ijọba ipinlẹ Ọṣun, lo ti ni ayẹyẹ ti ọdun yii ko ni i ni gbagba-gbugbu ninu.
Gẹgẹ bi Lawal ṣe sọ, idi ti ayẹyẹ Iṣẹṣe ti ọdun yii ko fi ni i lariwo ninu ni ti wahala ajakalẹ arun Koronafairọọsi to n lọ lọwọ lorileede yii.
Lorukọ gomina, Lawal ki awọn ẹlẹsin abalaye kaakiri ipinlẹ Ọṣun ku oriire ayẹyẹ ọdun naa, o si rọ wọn lati ṣọdun pẹlu alaafia, ki wọn si bọwọ fun ofin lasiko ayẹyẹ naa.
O tun bẹ wọn lati lo asiko naa lati gbadura fun idagbasoke ipinlẹ Ọṣun, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu iṣejọba to wa lode yii.
Bakan naa lo tun kilọ pe ki wọn tẹle gbogbo ilana to n dena itankalẹ arun korona, ṣaaju, lasiko ati lẹyin ọdun Iṣẹṣe.