*Mi o le dalẹ iyawo mi laelae, o ba mi jiya nigba ti nnkan ko ti i daa
Kamilu Kọmpo, Gọlugọ, Ọlẹyọ, Muniru eeyan Ambali, ẹni kan ṣoṣo naa lo n jẹ bẹẹ lagbo tiata Yoruba, Adekọla Tijani ni.
Ọjọ aboki ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ naa ti pẹ ninu obi jijẹ. O pẹ to ti n ba kinni ọhun bọ niluu Ọyọ pẹlu imulẹ rẹ ti i ṣe Sanyẹri (Afọnja Ọlaniyi). Kamilu Kompo funra ẹ royin, o tọ ilẹ la, lori irinajo ẹ nidii iṣẹ tiata fun ADEFUNKẸ ADEBIYI.
AKEDE AGBAYE: Ọdun wo lẹ bẹrẹ tiata?
GỌLUGỌ: Ṣaaju ohun gbogbo, a dupẹ f’Ọlọrun. Ko rọrun, ṣugbọn a dupẹ f’Ọlọrun ibi ta a ba a de ati ibi ta a ti bẹrẹ pẹlu ibi to n mu wa lọ.
Mo bẹrẹ iṣe ere, ere la pe e lọdun naa lọhun-un lọdun 1991, niluu Ọyọ. Mo bẹrẹ pẹlu ifẹ ti mo ni si i ati aayo ọkan. Ọga mi, Ọmọọba Ṣeyi Adeoye, k’Ọlọrun fori ji wọn lo kọ mi niṣẹ, emi ati Sanyẹri. Igba ta a bẹrẹ, a o mọ pe bo ṣe maa ri ree, a kan fi n ṣere ni, nitori inu wa maa n dun ba a ṣe n rawọn to n ṣe e lori tẹlifiṣan. Ṣugbọn mo dupẹ f’Ọlọrun lori ibi ti mo ba a de lonii.
AKEDE AGBAYE: Bawo ni irin ajo naa ṣe wa ri lati ọdun mọkandinlọgbọn tẹ ẹ ti n ba a bọ?
GỌLUGỌ: Alhamdulilai, ọpọ la jọ bẹrẹ nigba naa lọhun-un ti wọn ti ku, ọpọ lo ti taku sọna, nitori ko sohun to rọrun laye yii. Awọn to n jale gan-an atawọn gbọmọgbọmọ, wọn mọ pe ko rọrun, nitori ọjọ tọwọ pabala wọn ba maa segi.
Ti n ba ni ki n maa sọ gbogbo ohun toju ti ri, ti mo ba n sọ ọ latẹni dọla, mi o ni i mẹnu kuro nibẹ. Ẹ jẹ ka maa ba ọrọ yii bọ na, mo ṣi maa sọ ọ.
AKEDE AGBAYE: Ṣe famili lẹyin ati Sanyẹri ni, ẹ sun mọra yin pupọ?
GỌLUGỌ: A o ki i ṣe famili, ṣugbọn ọmọ Ọyọ kan naa jọ ni wa. Ibi ta a ti mọra ni pe a jọ maa n lọọ wo fiimu, a maa n pade daadaa nibẹ, ṣugbọn a ki i ta sira wa. O le lọdun kan ta a ti jọ maa n pade bẹẹ ka too maa sọrọ, mo maa n wo o pe nibo ni bọbọ yii ti maa n rowo waa wo fiimu bii temi bayii. Aṣe oun naa maa n ro o bẹẹ lọkan nipa mi. Nigba to ya lo lọọ darapọ mawọn to n ṣe tiata, mi o waa ri i nile sinima ta a ti maa n pade fun bii ọsẹ meji, lọjọ to wa ni mo waa beere lọwọ ẹ pe nibo lo lọ latijọ yii, o waa sọ fun mi pe oun darapọ mawọn onitiata ni. Mo sọ fun un pe o wu emi naa, pe ṣe mo le tẹle e lọ, o dẹ ni ko si wahala, a waa jọ lọ. Mo tiẹ ti n ro o lọkan mi pe ohun ti wọn fi gba iru bọbọ to kuru yii, wọn maa gba emi naa ṣaa ni, wọn dẹ gba mi loootọ, ba a ṣe bẹrẹ niyẹn l’Ọyọọ
AKEDE AGBAYE: Igba wo lẹ waa d’Ekoo?
GỌLUGỌ: 1995 la d’Ekoo, emi ti mọna Eko, nitori Eko ni mo ti ka pamari, oun o mọ Eko ni tiẹ ni 1995, ko ti i d’Ekoo ri. Igba ti mo pari pamari ni mo pada s’Ọyọọ, ti mo fi pade Sanyẹri yẹn. Emi naa ni mo mu imọran wa pe ko jẹ ka lọ s’Ekoo ni 1995, nigba ti sinima agbelewo ti n jade ni 1993, to dẹ jẹ Eko ni gbogbo wọn wa, mo waa ni ko jẹ ka lọ s’Ekoo, ko ma jẹ Ọyọ la kan maa jokoo si, o dẹ gba si mi lẹnu. Ba a ṣe jọ d’Ekoo niyẹn.
AKEDE AGBAYE: Ọdọ ta lẹ waa de si l’Ekoo?
GỌLUGỌ: Ọdọ sista mi ti mo ti maa n lọọ lo ọlude nigba ti mo wa l’Ekoo la de si. Ẹnu sitẹẹpu ile wọn lawa mejeeji n sun si, nitori yara kan ni aunti mi yẹn n gbe pẹlu ọmọ bii marun-un si mẹfa, ọkọ wọn naa dẹ tun wa nibẹ, awọn ọlọmọge dẹ wa ninu ọmọ wọn. A waa wo o pe ko si ba a ṣe fẹẹ maa sun laarin awọn wọnyi, ibi ta a le sun naa ni abẹ sitẹẹpu yẹn, ibẹ naa la bẹrẹ si i sun si. Tojo ba n rọ, a ni apo ta a maa n ta sibẹ ki afẹsi ojo ma baa maa fẹ si wa.
Ọdun mẹrin gbako la fi sun labẹ sitẹẹpu yii, sibẹ, nnkan ko rọrun fun wa, tiata ti a tori ẹ wa s’Ekoo ko yọ owo, ba a ṣe lọọ waṣẹ mi-in ṣe niyẹn.
Emi lọọ ṣiṣẹ burẹdi, oun lọọ ṣiṣẹ ṣuu meka ( shoe maker) ka le baa tu owo jọ. Igba ta a waa tu owo yẹn jọ la jọ gba yara kan, a waa jọ n gbe.
Igba to di 1996, a lọ sile ọdun l’Ọyọọ. Ile ọdun yẹn la ti pade Adebayọ Tijani, Ṣimiu, oun naa ṣi n gbiyanju lati la nigba yẹn ni, mo waa fun un ladirẹsi pe ko maa bọ nile ta a gba l’Ekoo, o dẹ wa, awa mẹtẹẹta waa tun jọ n gbe.
A o rowo gbale onibulọọku o, ile onipako ti wọn maa n kọ sori kanaali (canal) la gba. Ibẹ la ti bẹrẹ aye wa ni pẹrẹwu. A darapọ mọ ẹgbẹ Alaaji Akeem Ajala Jalingo, a ba awọn eeyan nibẹ daadaa, a dẹ bẹrẹ si i riṣẹ ṣe.
Awọn Ibrahim Chatta naa darapọ mọ wa, bo ṣaa ṣe di pe nnkan bẹrẹ si i jọra wọn diẹdiẹ niyẹn.
AKEDE AGBAYE: Ere wo lo waa gbe yin jade gan-an?
GỌLUGỌ: Ba a ṣe n jiya wa lọ niyẹn titi di 2009 ti mo ṣe ‘Kamilu Kọmpo’, igba yẹn ni Ọlọrun de sinu aye mi. Ko too digba yẹn ni mo ti niyawo, ere tiata niyawo mi naa n ṣe nigba yẹn, ọmọ ẹgbẹ Muyiwa Ademọla ni.
Ṣugbọn mo sọ fun un pe a o le jọ maa ṣiṣẹ yii lọ, nitori ati maa bojuto ile. Mo ni ṣe ki n fi tiata silẹ abi oun lo maa kuro, o dẹ loun maa kuro, bo ṣe fiṣẹ tiata silẹ niyẹn. Gbogbo igba yẹn, ko sowo nibẹ, bawo ni tọkọ-tiyawo aa ṣe maa jiya pọ ni mo ṣe ni kin ni ka ṣe, o dẹ gbọrọ si mi lẹnu.
Nitori ẹ ni mi o ṣe le dalẹ ẹ, nitori o ba mi jiya nigba ti nnkan ko ti i da.
AKEDE AGBAYE: Ẹ o jiya mọ bayii, okiki ti de, ṣe owo naa ti wa ?
GỌLUGỌ: Ṣe ẹ mọ pe tọmọde ba n lọ soko, adura koun lọọ ire, koun bọ ire, ni yoo maa gba, ko ni i ranti beere pe koun ri nnkan mubọ loko.
Nigba ta a n jiya kiri yẹn, adura ka lokiki, kaye mọ wa la n gba, a o ranti beere owo. Ṣugbọn a dupẹ f’Ọlọrun nibi to ṣe e de fun wa, nitori awọn mi-in naa ṣi wa ti wọn n fọla wa tọrọ bayii ni.
A ti n bẹ Ọlọrun ko ba wa fi owo kun un bayii ṣa, mo dẹ mọ pe o maa gba a, nitori o niye ọdun ta a fi tọrọ okiki naa ko too fun wa.
AKEDE AGBAYE: Iṣẹ yin yii le, ọpọ igba lẹ ẹ ki n gbele. Bawo lẹ ṣe n sinmi?
GỌLUGỌ: Haa, mi o le sinmi niluu yii rara.
Ki Korona too de, o yẹ ki n tirafu lọ si London lati sinmi, Koro ni ko jẹ ki n lọ.
Niluu yii, a fẹẹ lọọ ṣiṣẹ, a fẹẹ ṣe MC, awọn bọisi maa fẹẹ ri wa, famili naa wa nibẹ, foonu ko ṣaa ni maa dun keeyan ma gbe e, gbogbo iyẹn ki i jẹ ki n raaye sinmi.
Ti mo ba fẹẹ sinmi bẹẹ yẹn, mo maa n tirafu kuro ni Naijiria ni. Mo le lo oṣu kan tabi o kere tan, ọsẹ mẹta, ma a lọọ fi sinmi.
AKEDE AGBAYE: Fiimu meloo lẹ ti ṣe to jẹ tiyin?
GỌLUGỌ: Mejila.
AKEDE AGBAYE: Ounjẹ wo lẹ fẹran ju?
GỌLUGỌ: Amala ati gbẹgiri.
AKEDE AGBAYE: Ninu Korona lẹ da Kamkom TV, iyẹn tẹlifiṣan Kamilu Kompo silẹ, bawo leyi ṣe rọrun?
GỌLUGỌ: O ti wa ninu erongba mi tẹlẹ lati da a silẹ, sugbọn nitori ai saaye ti mo fi maa mojuto o funra mi ni ko jẹ ki n gbe e larugẹ bo ṣe yẹ.
Igba ti Covid 19 de ti mi o ṣe nnkan kan ni mo wo o pe mo le maa ṣe e funra mi bayii, bi mo ṣe bẹrẹ ẹ niyẹn. Awọn eeyan dẹ ti n wo o.
AKEDE AGBAYE: Bawo lẹ ṣe n gba ara yin lọwọ awọn onipaireesi ati makẹta tẹ ẹ maa n ri bii iṣoro iṣẹ yin?
GỌLUGỌ: Lasiko yii, ko sẹni to maa ṣe fiimu to maa ni oun ri ere, nitori gbogbo nnkan ti wọ́. Ohun ta a kan n ri ni orukọ, ohun la fi n tẹsiwaju.
Ko ri bayii tẹlẹ o, nitori mo ti ṣe fiimu ri ti mo ri èrè miliọnu mẹta, mo ti ṣe ri ti mo ri ere miliọnu meji. Ṣugbọn lasiko yii, ki n tiẹ ma lọ jinna, ni 2014 ni mo ṣe ‘Adigun relu oyinbo’, ti mo ba ṣi gbogbo owo ti mo fi ṣe e, aa wọ miliọnu mẹta.
Nigba ti mo fẹẹ ta a, mo ri i ta ni 1.2m, iyẹn miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba naira.
Mo ṣe ‘Zombie’ ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira (1.7m), mo ta ni 1m, miliọnu kan.
Ọkan tun wa ti mo fi miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna igba naira (2.2m) ṣe, mi o ti i mọ ibi ti mo n lọ lori ẹ bayii. Gbogbo awọn nnkan yẹn n ṣẹlẹ, nitori ọpọlọpọ nnkan lo ti wọ́.
Ṣugbọn a o le fi i silẹ lai ṣe, nitori Ọlọrun naa n gbe awọn alaaanu dide si wa.
Ẹlomi-in le wo ṣunṣun nisinyii ko ni ka waa boun ṣe MC, eelo lẹ fẹẹ gba, o le fun wa ni faifu ọndirẹdi taosan. Gbogbgo awọn nnkan ta a n jẹ lọdọ Ọlọrun bayii niyẹn.
AKEDE AGBAYE:Ẹ jẹ ka mọ awọn ileewe tẹ ẹ lọ
GỌLUGỌ: Mo lọ si Oyewọle Primary School, l’Agege. Mo pada siluu wa l’Ọyọọ, mo lọ sileewe Girama Ansarudeen, Ọpapa.
O ṣi wu mi lati tẹsiwaju si i, bo ṣe niluu oyinbo bo ṣe niluu yii, ma a tẹ ẹ.