Ọdun mẹtadinlọgọrin ni Abioye yoo lo lẹwọn, jibiti owo nla lo lu

Faith Adebọla, Eko

Ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹsun jibiti miliọnu mejilelọgọta ti Ọgbẹni Abioye Eluwọle n jẹ lọwọ, ẹwọn ọdun mẹtadinlọgọrin ni idajọ naa ba de.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni olujẹjọ naa tun fara han niwaju Adajọ Mojisọla Dada to n gbọ ẹjọ ọhun, ẹsun oriṣiiriṣii ti aropọ rẹ jẹ ọgbọn ni wọn ka si i lẹsẹ.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti EFCC ka niwaju adajọ, pataki lara awọn ẹsun naa ni pe olujẹjọ yii n ji ipin owo idokoowo awọn onibaara ileeṣẹ Bytofel Trust and Securities Limited, o si n ṣi agbara rẹ lo gẹgẹ bii ọga agba ileeṣẹ naa lati jale.

EFCC ni Eluwọle tun ji awọn ipin idokoowo to jẹ ti Ọgbẹni Donatus Okeke Ojumba atawọn ọmọ rẹ. Wọn ni gbogbo ele ori owo idokoowo tawọn eleebo n pe ni ṣias (shares) to yẹ kawọn ẹni ẹlẹni ri lọkunrin naa n re jọ sinu akanti tirẹ, to si n nawo wọn lọ bo ṣe wu u.

Wọn lawọn ẹsun wọnyi ta ko isọri irinwo din mẹwaa (390) ẹsẹ kẹjọ, ninu adipọ keji (Vol. 2) iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2003, ati isọri okoodinlọọọdunrun ati marun-un (285) ẹsẹ kẹsan-an iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2011 ni ipinlẹ Eko.

Bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ yii ta ku pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun yii, ẹlẹrii meji lo pe lati ro arojare rẹ, nigba ti ajọ EFCC to n ba a ṣẹjọ lorukọ ijọba pe ẹlẹrii marun-un ọtọọtọ, yatọ si obitibiti iwe ati akọsilẹ ti wọn ko siwaju adajọ lati fidi ẹsun wọnyi mulẹ.

Tori o ti ṣe diẹ ti ọkunrin naa ti n jẹjọ ọhun, inu oṣu kejila, ọdun 2018, ni wọn ti wa lẹnu ẹ, tawọn agbẹjọro rẹ si ti pari awijare wọn. Adajọ Mojisọla ni ko si ẹri to pọ to lati fihan pe olujẹjọ jẹbi mọkandinlogun ninu awọn ẹsun naa, tori naa, ile-ẹjọ ti da awọn yẹn nu.

Ṣugbọn o jẹbi mọkanla lara awọn ẹsun naa, arojare rẹ ko si nitumọ rara. Adajọ ni ko lọọ ṣẹwọn ọdun meje meje fun ọkọọkan awọn ẹsun mọkanla naa, eyi ti aropọ rẹ jẹ ọdun mẹtadinlọgọrin, ko si saaye fun owo itanran.

Adajọ tun ni ki olujẹjọ yii padanu awọn dukia rẹ pataki sọwọ ijọba, ki wọn si ta a lati fi san gbese owo olowo to ṣe baṣubaṣu, o si gbọdọ san gbese naa tan lai din kọbọ. Wọn ni ko ṣewọn naa papọ ni, ki wọn bẹrẹ si i ka ọjọ ẹwọn rẹ latigba ti wọn ti fi pampẹ ofin gbe e.

Leave a Reply