Ọdun to n bọ niṣẹ yoo pari patapata lori atunṣe biriji afara ẹlẹẹkẹta

Dada Ajikanje

Ni bayii ti ijọba apapọ ti pari atunṣe apa kan biriiji afara kẹta, iyẹn Third Mainland Bridge, l’Ekoo, wọn ti ni ko ni i si irinna rara lori biriiji ọhun fun wakati mejidinlogun, bẹrẹ lati aṣaalẹ  Abamẹta, Satide.

Oludari fun ileeṣẹ to n ṣatunṣe oju popo nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olukayọde Popoọla, lo kede yii lasiko to ṣabẹwo lori ibi ti wọn ba iṣẹ de.

O ni gbogbo eto lo ti pari nipa atunṣe ori afara ọhun si Oworonṣoki. Bẹẹ lo dupẹ lọwọ awọn awakọ gbogbo ti wọn n lo oju popo naa fun suuru wọn.

Ni bayii ti wọn ti pari abala akọkọ, o ti sọ pe gbogbo irinṣẹ atawọn panti to le maa dina fun lilọ bibọ ọkọ ni wọn maa ko kuro bayii, ti eto atunṣe yoo si bẹrẹ ni apa keji oju popo afara Third Mainland Bridge naa. O ni wakati mejidinlogun lawọn yoo fi gbe biriiji ọhun ti pa, ti ko ni i si lilọ-bibọ ọkọ rara.

Lati Satide, ọjọ Abamẹta, ni wọn ti ti ojuna naa, titi wọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla yii. Ohun ti wọn si n ṣe ni kiko awọn irinṣẹ atawọn panti kuro lojuna, bẹẹ gẹgẹ lo sọ pe awọn yoo ri i pe iṣẹ ọhun pari ki ilẹ ọjọ Aje, Mọnde, too mọ, nigba ti awọn awakọ yoo lanfaani lati maa lo apa kan ọna ọhun pada fun lilọ-bibọ wọn.

Popoọla sọ pe gbogbo awọn akiyesi lati ya soju popo mi-in naa ni yoo wa bo ti ṣe wa tẹlẹ, ati pe iṣẹ ti a fẹẹ ṣe bayii lati biriji Adekunle si Adeniji Adele Phase B, nigboro Eko.

Ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla yii, ni iṣẹ ọhun yoo bẹrẹ, ti yoo si pari lọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2021.

Ohun ti eyi tumọ si ni pe, oṣu mẹta gbako ni wọn yoo fi gbe apa kan biriji ọhun ti pa, lati Adekunle si Adeniji-Adele, ti atunṣe iṣẹ yoo maa lọ nibẹ.

Leave a Reply