Ọfẹ ni fọọmu idibo fawọn obinrin to ba fẹẹ dije dupo alaga ibilẹ ati kansilọ nipinlẹ Ogun- OGSIEC

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lati le le ṣe koriya fawọn obinrin, ki wọn si le lọwọ si oṣelu lai fi ti pe wọn jẹ abo ṣe, ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun, (Ogun State independent  Electoral Commission) OGSIEC, ti sọ pe ọfẹ ni fọọmu fawọn obinrin to ba fẹẹ dupo alaga ati kansilọ ninu idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2021.

Alaga OGSIEC, Ọgbẹni Babatunde Oṣibodu, lo sọ eyi atawọn ilana mi-in ti eto idibo naa yoo ṣamulo.

Ile aṣa ati iṣẹmbaye to wa ni Kutọ, l’Abẹokuta, ni Alaga ti sọrọ naa nigba to n ba awọn akọroyin atawọn oludije lẹgbẹ oṣelu sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu karun-un yii.

Ọṣibọdu ṣalaye nipa atunto to ba alakalẹ eto idibo naa. O ni laarin ọjọ karun-un, oṣu karun-un, si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun-un, ni awọn ẹgbẹ oṣelu yoo ṣe idibo abẹle wọn nipinlẹ Ogun. Gbogbo ipolongo ibo yoo si dopin loru Ọjọbọ, ọjọ kejilelogun, oṣu karun-un, ọdun 2021.

Nipa awọn oludije to fẹẹ kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ yii, ṣugbọn ti wọn ṣi wa ninu igbimọ afunnṣọ lawọn ijọba ibilẹ Ogun to wa nipinlẹ Ogun, Alaga OGSIEC sọ pe wọn gbọdọ fi ipo naa silẹ, o pẹ ju, ọgbọn ọjọ si ọjọ kẹrinlelogun ti idibo fẹẹ waye.

Lori iye owo fọọmu ti wọn foju fo fawọn obinrin, Ọṣibodu sọ pe fun ipo alaga lọkunrin, ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) lowo fọọmu, nigba ti tawọn kansilọ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (100,000).

Owo yii ko ṣee da pada bi alaga ṣe wi, ẹni to ba ti san an pe oun fẹẹ kopa ti san an naa niyẹn.

Alaga OGSIEC to sọrọ pẹlu idaniloju gidi sọ pe eto idibo eleyii yoo lọ ni irọrun, akoyawo gidi yoo si wa nibẹ pẹlu, o ni ko sẹni kan ti yoo fi igba kan bọ ọkan ninu.

O waa kilọ fawọn ẹni ibi to n jẹ nidii madaru, ti wọn le fẹẹ doju eto idibo ijọba ibilẹ yii delẹ. Ọṣibodu sọ pe gbogbo eto lo ti to fun iru awọn wọnyi, wọn yoo si ba ijọba nibẹ bii aba.

Bakan naa lo rọ awọn oludije lati tẹle gbogbo ilana tuntun ti ajọ yii gbe kalẹ, o ni bi ṣiṣi ni ilẹkun OGISIEC wa, ẹnikẹni le waa sọ ero ọkan rẹ, kawọn si jọ gbe e yẹwo fun ilọsiwaju.

Leave a Reply