Ọfiisi Ajọ eleto idibo jona l’Akurẹ

Ọfiisi Ajọ eleto idibo to wa niluu Akurẹ, ni olu-ilu ipinlẹ Ondo, ti jona.

Lasiko ta a n kọ iroyin yii, ko sẹni to le fidi ohun to fa ijamba naa mulẹ, ṣugbọn a gbọ pe bii maṣinni ẹgbẹrun marun-un ti wọn fẹẹ fi ka ibo lo jona.

Bii aago mẹsan-an alẹ ku diẹ ni ina naa sọ, ẹka kọmputa ileeṣẹ naa ni kinni ọhun si ti ṣẹlẹ, bẹẹ lawọn panapana ko ti i debẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Fidio:

 

Leave a Reply