Ofin konilegbe Eko ti di aago mẹfa aarọ si mẹjọ alẹ

Faith Adebọla

Ijọba Eko ti kede pe ayiada ti ba asiko konilegbele ti wọn ti kede rẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.

Lati ọjọ Aiku ọsẹ yii, awọn araalu lanfaani lati aago mẹfa aarọ di aago mẹjọ alẹ. Lati aago mẹjọ alẹ, ko sẹni to gbọdọ jade mọ.

Eleyii yatọ si aṣẹ ti ijọba Sanwo-Olu pa tẹlẹ pe aago mẹjọ aarọ ni ki awọn eeyan maa jade, ki wọn maa wọle pada laago mẹfa irọlẹ.

O rọ awọn araalu lati fi eto si irinajo wọn bi wọn ṣe n jade lọ sẹnu iṣẹ wọn.

Leave a Reply