Ofin ti yoo fiya jẹ obi ti ọmọ ẹ ba n sẹgbẹ okunkun n bọ l’Ekoo

Faith Adebola, Lagos

Bi abadofin kan tawọn aṣofin Eko ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ bayii ba fi dofin, ki i ṣe ọmọ ti wọn ba mu pe o jẹbi ṣiṣe ẹgbẹ okunkun nipinlẹ naa nikan ni yoo jiya, wọn yoo bẹrẹ si i fi pampẹ ofin gbe obi irufẹ ọmọ bẹẹ, tawọn naa yoo si fimu kata ofin pẹlu.

Awọn aṣofin lo sọ eyi di mimọ nibi apero wọn to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lasiko ti wọn n fi erongba wọn han lori abadofin kan ti Amofin agba fun ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Moyọsọrẹ Onigbajo, fi ṣọwọ si wọn.

Olori wọn, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, sọ pe ‘o yẹ lati fi iyatọ saarin ẹgbẹ gidi ati awọn ẹgbẹ okunkun, awọn ohun ija ti wọn n ko kiri, ati ofin to de ṣiṣe ẹgbẹ ti a ti n lo bọ tẹlẹ, ko ma lọọ jẹ pe ibi ta a ti fẹẹ yanju iṣoro kan la tun ti maa da omi-in silẹ.

Olori aṣofin to pọ ju ninu ile naa, Ọnarebu Ṣaina Agunbiade, sọ pe ọpọ awọn ẹgbẹ okunkun lo lawọn baba isalẹ to n ṣonigbọwọ fun wọn, bẹẹ si lawọn obi tọmọ wọn n ṣẹgbẹkẹgbẹ naa yẹ ki wọn maa fara gba ijiya ofin pẹlu.

O ni o yẹ lati ṣewadii daadaa ki wọn too sọ pe ẹnikan jẹbi ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, tabi ki wọn too le irufẹ ọmọ bẹẹ danu nileewe.

Ni bayii, Ọbasa ti taari abadofin naa si igbimọ ile to n rí si eto idajọ pe kí wọn ṣiṣẹ lori ẹ, ki wọn si jabọ fun ile laarin ọsẹ mẹta.

Leave a Reply