Ofofo wa ti wọn ṣe la fi ṣeku pa awọn agbẹ bii ọgọrin ni Borno – Boko Haram

Jide Alabi

Ẹgbẹ afẹmiṣofo nni, Boko Haram, ti sọ pe awọn gan-an lawọn ṣeku pa awọn agbẹ to le ni ogoji laipẹ yii, nipinlẹ Borno.
Olori awọn janduku yii, Abubakar Shekau, ti sọ pe eeyan mejidinlọgọrin (78) lawọn pa, ki i ṣe mẹtalelogoji (43) lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ gẹgẹ bí ijọba ṣe kede ẹ.

Ninu fidio kan ti awọn afẹmiṣofo yii fi sita ni wọn ti sọ pe niṣe lawọn yoo maa kọ lu gbogbo eeyan to ba ti n ṣofofo awọn fun ileeṣẹ oloogun tabi ẹṣọ yoowu to jẹ ti ijọba to le ko idaamu ba awọn.

Ọkunrin yii fi kun ọrọ ẹ pe ohun to fa iku ojiji t’awọn fi pa awọn agbẹ onirẹsi ọhun ko ju bi wọn ṣe fa ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ awọn le awọn agbofinro lọwọ lọ. Ati pe ẹnikẹni to ba tun ṣe bẹẹ, niṣe lawọn yoo maa ṣe ẹmi iru ẹni bẹẹ lofo atawọn eeyan to ba sun mọ wọn.

Tẹ o ba gbagbe, iṣẹlẹ buruku yii ti ṣẹlẹ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ni Zabarmari, nijọba ibilẹ Jere, nipinlẹ Borno, lasiko ti awọn agbẹ naa wa ninu oko ti wọn n ja irẹsi ni awọn Boko Haram yii kọ lu wọn, ti wọn si bẹ ori wọn da silẹ bii igba teeyan bẹ aja.

Ọkan ninu awọn afẹmiṣofo yii to ti n yọ awọn araalu naa lẹnu lawọn eeyan ọhun mu, ti wọn si gba gbogbo ohun ija oloro to fi n ṣọsẹ, ki wọn too fa a le agbofinro lọwọ. Eyi la gbọ pe o bi awọn ikọ aṣekupani yii ninu ti wọn fi kọ lu awọn agbẹ ọhun, ti wọn si pa wọn lọ rẹpẹtẹ.

Latigba naa ni oriṣiriiṣii awuyewuye ti n wáyé nipa iye awọn ti wọn pa gan-an. Ọtọ niye ti ijọba apapọ sọ, bẹẹ ọtọ ní iye ti ìjọba ìpínlẹ̀ Borno náà kéde, ti ileeṣẹ tẹlifíṣàn CNN naa si tun sọ pe awọn eeyan to ku le ni ọgọrun-un daadaa.

Bẹẹ lọrọ ọhun paapaa ti mu oríṣiiríṣii eeyan atawọn ẹgbẹ oṣelu alatako kọ lu Ààrẹ Muhamadu Buhari, t’awọn kan si n sọ pe eto ijọba Naijiria ti daru mọ ọn lọwọ patapata.

Leave a Reply