Ọga ṣọja kilọ fawọn ọmọ ẹ: Ẹnikẹni o gbọdọ dabaa fifipa gbajọba ninu yin o

Faith Adebọla, Eko

Olori awọn ṣọja ilẹ wa, Ọgagun Tukur Buratai, ti ṣekilọ to lagbara fawọn ọgagun to wa nileeṣẹ ologun, awọn jẹnẹra gbogbo, pe kẹnikẹni ma ṣe dabaa ati fipa gbajọba awa-ara-wa orileede yii.

Nibi ayẹyẹ igbega ti wọn ṣe fawọn ọgagun tuntun mọkandinlogoji ti wọn ṣẹṣẹ bọ sipo Mejọ-jẹnẹra l’Abuja, lọjọ Ẹti, Furaidee, ni Buratai ti sọrọ ọhun, o ni ileeṣẹ ologun ilẹ wa ko ni i fara mọ ki ẹnikẹni fibọn da eto oṣelu to wa lode yii ru.

Buratai ni awọn n gbọ finrin-finrin pe awọn oloṣelu kan ti n pa kubẹkubẹ lọọ ba awọn ọgagun nileeṣẹ ologun, ti wọn n fẹ lati fa oju wọn mọra, o ni kawọn ọgagun naa ṣọra o, tori toju-tiyẹ laparo ileeṣẹ ologun fi n riran lasiko yii, gbogbo bo ṣe n lọ lawọn n kiyesi.

“Ijọba dẹmokiresi gbọdọ fẹsẹ rinlẹ ni. A o fẹ awọn to maa dabaru ẹ. Gbogbo ọdun tijọba ologun fi ṣakoso ko gbe wa debi kan, iyẹn naa si ti to.

“Gbogbo oju lo n wo yin o. Ẹ ma ṣe wọle-wọde pẹlu awọn oloṣelu, ẹ ma sọ pe ẹ n wa ipo kan. Tẹ ẹ ba fẹ ipo, olori ologun ni kẹ ẹ ba sọ ọ. Ẹ ma ṣe ohunkohun to maa tapo si aala ileeṣẹ ologun tabi ofin ilẹ wa o,” Buratai lo ṣekilọ bẹẹ.

Leave a Reply