Ọga agbẹjọro kan lati orileede France ni yoo ṣiwaju awọn lọọya ti yoo duro fun Sunday Igboho ni kootu Benin

Jọke Amọri

 Iroyin to n tẹ ALAROYE lọwọ bayii lori ọrọ ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ni pe yatọ si Agbẹjọro Yọmi Alliu atawọn mi-in ti wọn jẹ ọmọ Yoruba ti wọn n duro fun Oloye Igboho, wọn ti tun yan ọmọ bibi orileede Benin kan ti a forukọ bo laṣiri, to fi orileede France ṣebugbe lati darapọ mọ awọn ti yoo gba ẹjọ ajijagbara naa ro niwaju adajọ.

Ọmọ bibi ilu Benin ni agbẹjọro yii gẹgẹ bi awọn to mọ bo ṣe n lọ lori ọrọ naa ṣe yọ sọ fun ALAROYE.

Ọkunrin naa jẹ ọkan pataki ninu awọn agbẹjọro to dantọ niluu naa, oun naa si yoo si ṣaaju awọn agbẹjọro ti yoo gbẹjọ rẹ ro niwaju adajọ.

ALAROYE gbọ pe orileede France lo n gbe, to ti n ṣiṣẹ amofin, ṣugbọn o ni ileeṣẹ ofin rẹ ni orileede Benin, bẹẹ lo si jẹ ọmọ Yoruba orileede naa.

Awọn to yọ ọrọ yii sọ fun akọroyin wa sọ pe ọkunrin naa jẹ gbajumọ lorileede naa, o si wa ninu awọn to kọ ofin orileede Benin. Nitori pe o jẹ ọmọ oniluu, to si jẹ ọmọ Yoruba, ireti wa pe yoo le ṣoju fun Sunday Igboho daadaa.

Yatọ si ọkunrin yii a gbọ pe agbẹjọro mi-in naa tun wa lati ilẹ Benin, ti oun naa yoo duro fun un.

A gbọ pe awọn agbẹjọro to n ṣiṣẹ labẹ rẹ ti darapọ mọ awọn agbẹjọro Sunday Igboho nile-ẹjọ ba a ṣe n sọ yii, ireti si wa pe ọkunrin agbẹjọro agba naa yoo darapọ mọ wọn laipẹ rara.

Gbogbo ipa ati agbara ni awọn agbaagba Yoruba kan atawọn Yoruba to wa niluu oyinbo n ṣa lati ri i pe ọrọ naa ja sibi to daa.

Ẹnikan to ba ALAROYE sọrọ ti ko fẹ ka darukọ oun ninu awọn majẹobajẹ naa sọ pe ohun to fa a ti awọn fi mura si ọrọ yii ni pe ẹtẹ awo ni ẹtẹ ọgbẹri.   O ni ti oju ba ti Sunday Igboho, gbogbo Yoruba ni oju ti, idi niyi ti awọn fi n sa gbogbo ipa lati ri i pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ ati pe ajijagbara naa jade lai fara pa.

Leave a Reply