Ọga ileewe to ba gba owo tijọba ko fọwọ si lọwọ akẹkọọ yoo da ara rẹ lẹbi. 

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Kọmiṣanna feto ẹkọ ileewe giga imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ (Tertiary Education, Science and Technology), Hajiya Sa’adatu Modibbo Kawu ti sọ pe ọga ileewe to ba gba owo ti ko tọ, tabi eyi tijọba ko fọwọ si yoo da ara rẹ lẹbi.

Kawu ni ikilọ naa ṣe pataki latari iroyin tijọba n gbọ pe ileewe College of Arabic and Islamic Legal Studies (CAILS), n gba owo lọwọ awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ wọle nitori bi wọn ṣe kọ lati gbe inu ile to wa lọgba ileewe naa.

O koro oju si iru igbesẹ bẹẹ, o si ke si gbogbo awọn adari ileewe giga to jẹ tipinlẹ Kwara lati tete jawọ.

Kawu ni, “Ijọba yii mọ iṣoro tawọn eeyan n la kọja bayii, a ko si fẹ ohun to tun le dakun un”.

Kọmiṣanna ti waa paṣẹ fun gbogbo ileewe giga patapata lati ma fi owo kun owo ileewe, owo igbaniwọle, owo ositẹẹli atawọn mi-in fun saa ikẹkọọ tuntun yii.

Atẹjade lati ọwọ Akọwe iroyin Kọmiṣanna naa, Ọgbẹni Adamu M. Saidu, ni ijọba ti gbe igbimọ meji ọtọọtọ kalẹ lati ṣewadii iru iṣẹlẹ naa nileewe International Aviation College ati ileewe gbogboniṣe,  Kwara State Polytechnic.

Leave a Reply