Ọga kọsitọọmu ku sibi to ti lugọ de awọn onifayawọ ni Ṣaki

Olu-Theo Ọmọlohun, Oke Ogun

 

 

Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n ṣawuyewuye nipa iku ojiji to pa ọga aṣọbode kan lagbegbe Ṣaki, Ọgbẹni Johnson Olufẹmi. Awọn eeyan kan ti n sọ pe ọrọ iku rẹ ki i ṣoju lasan, ileeṣẹ kọsitọọmu si ti lawọn maa ṣewadii nipa ẹ.

Awọn to n jẹ ẹ lẹnu pe iku naa ki i ṣoju lasan sọ pe nnkan to mu ki awọn ro bẹẹ ni pe ipo ẹlẹgẹ nipo ti oloogbe naa wa, wọn ni ọkan lara awọn ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ kọsitọọmu ni, oun ni wọn yan lati maa ṣiṣẹ itọpinpin awọn onifayawọ ati ẹru ti wọn ba ko lagbegbe naa.

Ọjọ Abamẹta, Satide, to lọ yii la gbọ pe oloogbe naa to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Edo ṣi ṣaaju ikọ aṣọbode kan lati lọọ dena de awọn onifayawọ tolobo ta wọn pe wọn fẹẹ ko awọn ẹru ti ko bofin mu kan wọlu lati orileede olominira Togo, wọn loun atawọn ọmọọṣẹ rẹ kan ni wọn lọọ lugọ de awọn onifayawọ ọhun.

Iwadii wa fi han pe inu igbo ti wọn fara pamọ si naa ni nnkan kan ti ṣẹlẹ soloogbe ọhun lai ro ti, wọn ni bi wọn ṣe fẹẹ gbera lọọ pade awọn onifayawọ naa nigba ti wọn ti n gburoo wọn, ibẹ naa ni ko ti ṣee ṣe fun un lati dide, bo tilẹ jẹ pe awọn kọsitọọmu to ku ko tete fura pe nnkan ti ṣẹlẹ.

Wọn ni igba tawọn ọmọọṣẹ naa reti pe ki ọga wọn paṣẹ bo ṣe maa n ṣe lati ṣina bolẹ fawọn onifayawọ, ti wọn o si gburoo kan titi tawọn onifayawọ naa fi fẹẹ kọja tan, lara too fu wọn, ni wọn ba lọọ wo ọkunrin naa nibi to wa, ṣugbọn nnkan iyalẹnu ni wọn ba, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin, Olufẹmi ti dagbere faye.

Ọga agba awọn kọsitọọmu lagbegbe naa, CSC B. J. Ọdẹdeji ati ọga agba to wa fun iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ (Customs Intelligence Unit), Ọgbẹni Richard Adegoke sọ fakọroyin wa pe kiakia lawọn ti gbe ọkunrin to lomi lara naa wa sileewosan Baptist Hospital to wa niluu Ṣaki, boya wọn ṣi le rọgbọn da si i, ṣugbọn dokita sọ fun wọn pe ẹni ti wọn gbe wa ti ku, aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan n sọ pe aisan rọpa-rọsẹ n ba baba naa finra fun ọjọ pipẹ tẹlẹ, ti wọn lo si ti n gbadun, ṣugbọn Ọgbẹni Adegoke ni ko sohun to ṣe oloogbe yii kiṣẹlẹ ọjọ naa too waye, bẹẹ ni Ọdẹdeji ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii ẹni ti ki i fi iṣẹ rẹ ṣere, wọn lo jafafa gidi, o si fi ara rẹ jin gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede rere.

Atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ lati ileeṣẹ aṣọbode fihan pe wọn maa sinku oloogbe yii lọjọ Abamẹta, Satide, to n bọ yii ni itẹkuu Vault and Garden Cemetry, to wa n’Ikoyi, l’Ekoo, lẹyin eto aisun onigbagbọ ti wọn fẹẹ ṣe fun un lọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii.

Iyawo kan ati ọmọ mẹta ni wọn ni ọkunrin yii fi saye lọ

Leave a Reply