Faith Adebọla
Ẹgbẹ kan to n ja fun ijangbara awọn ọmọ Yoruba, Ilana Yoruba, ti kọ lẹta si Ọga agba awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, lori iwọde ti wọn fẹẹ ṣe niluu Eko ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun yii. Koko ohun to wa ninu lẹta naa to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe kọmiṣanna naa ko laṣẹ labẹ ofin lati di awọn lọwọ pe ki awọn ma ṣe iwọde naa nitori ẹtọ awọn ni labẹ ofin ilẹ wa lati ṣe bẹẹ.
Ninu lẹta naa ti Akọwe ẹgbẹ ọhun, Ọpẹoluwa Akinọla, fọwọ si, lo ti sọ pe ‘‘Wọn ti pe akiyesi ẹgbẹ wa si ọrọ ti o sọ nibi ipade oniroyin ti o ṣe pe o lodi si iwọde alaafia ti a fẹẹ ṣe niluu Eko ni ọjọ kẹta, oṣu keje, ọdun yii.
‘‘Inu wa dun pe iwọ naa ti mọ nipa iwọde alaafia to fẹẹ waye niluu Eko yii, inu wa si tun dun pe iwọ funra rẹ fẹnu ara rẹ sọ ọ pe iwọde alaafia ni a sọ pe a fẹẹ ṣe niluu Eko, bo tilẹ jẹ pe o sọ pe o ko gbagbọ pe iwọde naa yoo jẹ ti alaafia gẹgẹ bi a ṣe sọ. Bakan naa ni a ṣakiyesi ihalẹ ti o n ṣe lati tẹ ẹtọ awọn to fẹẹ darapọ mọ iwọde yii loju.
‘‘Ṣugbọn a fẹ ki o mọ pe iwọde yii kọ ni yoo jẹ akọkọ tabi ikẹyin, latọwọ awọn to ṣeto rẹ lati fi ta awọn ọmọ Yoruba ji, ninu eyi ti iwọ naa wa, lori ẹtọ ti wọn ni labẹ ofin lati ja fun ẹtọ wọn.
‘‘A fẹẹ fi asiko yii sọ fun ọ pe iwọde naa yoo waye gẹgẹ bii ẹtọ wa labẹ ofin.’’
‘‘Gbigbe akọle lọwọ lasiko iwọde jẹ ọna kan lati fi ẹdun ọkan ẹni han si ijọba lori bi nnkan ṣe n lọ. Yoo jẹ iwa ojududu tabi ti ifasẹyin fun orileede kan lati maa gba iwe aṣẹ ka too ṣe iwọde nibi ti aye laju de yiijẹ ki ijọba mọ bi nnkan
Bakan naa lo sọ pe inu awọn dun pe kọmiṣanna naa sọ pe awọn kan le fẹẹ ja iwọde yii gba, ṣugbọn eyi ko gbọdọ di ẹtọ ti awọn ni labẹ ofin lọwọ lati ṣe e. Bẹẹ lo sọ pe kọmiṣanna Eko ko lagbara labẹ ofin lati da iwọde naa ru, ojuṣe rẹ gẹgẹ bii ọga ọlọpaa ni lati pese eto aabo fun awọ ti ẹnikẹni ko fi ni i da iwọde naa ru.
Akinọla ni, ‘‘A waa rọ ọ gẹgẹ bii ọmọ Naijiria ti wọn kọ ọ re lati ma ṣegbe lẹyin ẹnikẹni lasiko iwọde yii, ki o si pese aabo to tọ fun wa lasiko iwọde naa gẹgẹ bi awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Ogun, Ondo, Ekiti, Ọṣun ati Kwara ti ṣe fun wa, ti wọn si ri i pe awọn iwọde to waye lawọn agbegbe awọn lọ ni alaafia.
‘‘Bakan naa la rọ ọ pe ki o sọ fun awọn ọmọọṣẹ rẹ ki wọn ma doju ija kọ awọn oluwọde, nitori a ti pe akiyesi ajọ agbaye ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ kaakiri agbaye si awọn ọrọ ti o n sọ si iwọde ti a fẹẹ ṣe yii, ẹnikẹni ti o ba si hu iwa ti ko dara si wa lasiko iwọde yii yoo jẹjọ to ba yẹ lori rẹ.’’