Ọga ọlọpaa ku sotẹẹli lasiko to n ṣe ‘kinni’ fun obinrin to gbe lọ sibẹ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan
Ibi ti ọga ọlọpaa kan gba wa saye naa lo ba pada sọrun pẹlu bi ọkunrin naa ṣe jẹ Ọlọrun nipe lẹyin ọpọlọpọ ibalopọ to ṣe pẹlu obinrin kan to gbe lọ si otẹẹli kan niluu Ibadan.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹta kọja diẹ ni Insipẹkitọ ọlọpaa ọhun, Micheal Ogunlade, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta gbe obinrin kan ti wọn ni opo ni, ọkọ rẹ ti ku, lọ si otẹẹli to wa laduugbo Oke-Ado, niluu Ibadan.
Ni nnkan bii aago mẹta kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ni wọn wọle si otẹẹli naa, ti wọn si gba yara ti wọn maa n pe ni ṣọọti taimu, iyẹn ni pe akoko diẹ ni wọn fẹẹ lo lotẹẹli ọhun, ki wọn tura tan, ki wọn si jade ni.
Ṣugbọn ko pẹ pupọ ti wọn wọle ti obinrin to gbe lọ naa fi pariwo lọ sọdọ awọn olotẹẹli nisalẹ pe ọkunrin naa ko mi daadaa mọ.
Oju-ẹsẹ ni awọn yẹn sare pe awọn ọlọpaa ni Iyaganku, ṣugbọn ki awọn yẹn too maa du ẹmi rẹ lati gbe e lọ sọsibitu, ọkunrin naa ti kọja sodi-keji.
Awọn kan sọ pe niṣe ni ọlọpaa ọhun lu magun lara obinrin to gbe lọ si oteeli naa, wọn ni ọkunrin kan ti fi magun le e lara. Ṣugbọn awọn mi-in n sọ pe oogun amarale ni ọkunrin naa lo to fi ba obinrin yii sun.
O jọ pe oogun yii lo ṣiṣẹ gbodi fun ara rẹ ti ọkan rẹ fi daṣẹ silẹ, to si gbabẹ ku.

Leave a Reply