Ọga ọlọpaa patapata ṣabewo ibanikẹdun si Sanwo-Olu atawọn ọmọọṣẹ rẹ l’Ekoo

Jide Alabi

Ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Ọga agba ọlọpaa patapata nilẹ wa, Muhammed Adamu, ṣabẹwo si ipinlẹ Eko, lati ki Gomina Babajide Sanwo-Olu pẹlẹ ti ajalu to ṣẹlẹ nipinlẹ naa, nibi ti ọpọ ẹmi ati dukia ti ṣofo latari bi awọn ọmọọta kan ṣe ja iwọde SARS tawọn ọdọ n ṣe gba, ti wọn si n lo asiko naa lati jale, ati lati ba oriṣiiriṣii nnkan jẹ.

Ọga ọlọpaa naa ni oun waa ba Sanwo-Olu kẹdun lori bi awọn janduku naa ṣe ba ọkẹ aimọye dukia ipinlẹ Eko ati ti awọn aldaani jẹ, ti ọpọ ẹmi si tun ba iṣẹlẹ aburu naa lọ.

Bẹẹ lo tun lo asiko naa lati da awọn ọmọ iṣẹ rẹ lọkan le nitori bi awọn kan ninu wọn ṣe ba iṣẹlẹ naa lọ, ti awọn janduku naa si tun dana sun ọpọlọpọ agọ ọlọpaa. O ni ki wọn ma jẹ ki akọlu ti awọn ọmọọta yii ṣe si awọn ọlọpaa ati agọ wọn kaakiri orileede yii omi tutu si wọn lọkan.

Nigba to n sọrọ nile ijọba to wa ni Marina, l’Ekoo, lasiko abẹwo rẹ, Adamu sọ pe, oun waa ṣe abẹwo si awọn agọ ọlọpaa ti wọn bajẹ lati ri ipo ti gbogbo nnkan wa. O waa rọ awọn ọlọpaa pe ki wọn ri iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ara ipenija to rọ mọ isẹ wọn.

Ọga ọlọpaa yii ni bi a ko ba ni i purọ, iṣẹlẹ naa da omi tutu si ọkan awọn agbofinro kaakiri, ṣugbọn oun rọ wọn lati mu ọkan le, ki wọn si ri iṣẹlẹ naa bii ohun ti iṣẹ wọn pe fun lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.

Leave a Reply