Ọga ọlọpaa patapata bẹ awọn ọmọọṣẹ rẹ: A maa san ẹkunwo fun yin, ẹ ma daṣẹ silẹ o

Adewumi Adegoke

Latari ipinnu awọn ọlọpaa ilẹ wa lati bẹrẹ iyanṣẹlodi nitori ẹkunwo ti wọn n beere fun ti wọn ni awọn ọga awọn ko ja kunra, Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Usman Baba, ti ṣeleri pe ki awọn agbofinro naa ma foya rara, o ni laipẹ lai jinna ni wọn yoo ri ẹkunwo lori owo-oṣu wọn. O sọ pe Aarẹ Buhari ti fọwọ si sisan owo naa to ni yoo bẹrẹ laipẹ.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo sọrọ naa, eyi ti Igbakeji ọga ọlọpaa to wa fun (Iwadii , Eto ati Amojuto) Johnson Babatunde Kokumọ, gbẹnu rẹ sọ lasiko to ṣabẹwo si ẹka Zone 2 ti ipinlẹ Ogun ati Eko wa.

O ni nnkan eewọ ni pe ki awọn ọlọpaa daṣẹ silẹ. O ṣalaye pe ẹka ijọba apapọ to wa nidii iru eto to jẹ mọ owo sisan yii ti n ṣiṣẹ lori rẹ, wọn si ti fẹrẹ pari akojọpọ ati ayẹwo orukọ. O ni ki i ṣe nnkan ti wọn yoo kan ku giiri ṣe, nitori awọn igbesẹ naa ni lati ba awọn ẹka ileeṣẹ ijọba kan kọja. O fi da awọn eeyan naa loju pe Aarẹ ti buwọ lu ẹkunwo yii, ko si sẹni to le da a pada. Bakan naa lo ni ijọba yọ owo-ori kuro ninu owo-oṣu awọn, eyi to tumọ si pe wọn ko ni i maa gba owo ori lori owo-oṣu tawọn ba n gba mọ.

Siwaju si i, o ni ọga ọlọpaa ti paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọọ fi imọ kun imọ si i, bakan naa lo ni ki wọn gba awọn ọlọọpaa si i, ki wọn si ṣatunṣe awọn baraaki ti wọn n gbe.

Bẹẹ lo ni ọga ọlọpaa ti paṣẹ fun gbogbo awọn kọmiṣanna kaakiri ipinlẹ lati wa asi olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja lati waa gba awọn ohun eelo ti wọn yoo maa lo lati mu ki iṣẹ wọn rọrun si i.

O rọ wọn ki wọn ni suuru diẹ si, ki wọn si ma feti si awọn ti ko nikan an ṣe ti wọn n pariwo iyanṣẹlodi, o ni ko si ninu aṣa awọn agbofinro lati maa daṣẹ silẹ.

O ni yatọ si awọn ohun meremere ti ileeṣẹ ọlọpaa ati ijọba apapọ ti ṣe fun wọn, awọn araalu paapaa ti ṣe awọn ohun to dara fun awọn ọlọpaa, wọn ko si gbọdọ ja wọn kulẹ lasiko yii.

Kokumọ rọ awọn agbofinro naa lati yago fun awọn iwa ti ko ba ofin ati ilana iṣẹ ọlọpaa mu, ki wọn si tele aṣẹ ati ilana to yẹ ni titẹle to n ṣe atọna fun iṣẹ ọlọpaa ti wọn n ṣe.

Ọga ọlọpaa ni, ‘‘O yẹ ki ẹ maa ranti akọmọna wa nigba gbogbo, eyi to sọ pe ‘ọrẹ yin ni ọklọpaa’, ti ẹ ba wa n si agbara yin lo fun awọn to jẹ pe owo-ori ti wọn ba san ni wọn fi n sanwo oṣu yin, kẹ ẹ ranti pe wọn n wo wa lẹyin; ti ẹ ba ṣe daadaa, awọn araalu yoo yin yin, ti ẹ ba ṣe aidaa, awọn araalu yoo bu yin.’’

Bakan naa lo ni awọn ko dakẹ lori eto igbega fun awọn ọlọpaa yii. O ni awọn n ṣiṣẹ lori rẹ, awon to ba si tọ si igbega ninu wọn yoo gba a laipẹ jọjọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Alabi dupẹ lọwọ igbakeji ọga ọlọpaa naa fun bo ṣe gbọn ẹru to n ba awọn agbofinro lori ọrọ owo-oṣu naa nu, to si ṣeleri ifaraji ọtun fun iṣẹ wọn.

Leave a Reply