Ọga ọlọpaa tuntun bẹrẹ iṣẹ nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan
Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii ti gbe CP Adebọwale Williams lọ si ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bii ọga agba tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ. L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lo bẹrẹ iṣẹ.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade to fi ranṣẹ sawọn oniroyin n’Ibadan.

Ọkunrin ọmọ bibi ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo yii, lo wọ iṣẹ agbofinro lọjọ kejidinlogun, oṣu karun-un, ọdun 1992, to si ti ni iriri pupọ lẹnu iṣẹ naa nitori ọpọlọpọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa lo ti ṣiṣẹ sẹyin.
Lara awọn ipinlẹ ti iṣẹ ọhun ti gbe e lọ sẹyin ni ipinlẹ Enugu, Gombe, Niger ati Jos. Bẹẹ lo ti lọọ ṣoju orileede yii nibi ipẹtusaawọ lorileede Sierra-Leone.
Ọkunrin to kẹkọọ nipa imọ ofin yii ṣẹṣẹ gba agbega sipo ọga agba ọlọpaa ipinlẹ ti wọn n pe ni CP ni, Ọyọ si ni ipinlẹ akọkọ ti yoo ti bẹrẹ iṣẹ nipo rẹ tuntun naa.
CP Adebọwale lọga agba ọlọpaa kẹrinlelogoji nipinlẹ yii.
Ni ti Onadeko ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, AIG Ngozi Onadeko, oun ti di igbakeji ọga agba patapata bayii, o si jẹ ọkan ninu awọn igbakeji ọga agba ọlọpaa ọlọpaa orileede yii ti yoo maa mojuto awọn nnkan ija ileeṣẹ agbofinro.

Leave a Reply