Ọgba ẹwọn ni Ahmed yoo ti sọdun tuntun o, ọmọ lanlọọdu ẹ lo ba lo pọ n’ Ilọrin 

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Olukọ ileewe ijọba kan, Ahmed Yusuf, tọwọ tẹ laipẹ yii pe o n ba ọmọ ọdun mejila kan laṣepọ, to si n fi iku halẹ mọ ọn pe to ba sọ fun ẹnikan, oun yoo pa a, ti dero ọgba ẹwọn bayii.

Adajọ Shade Lawal tile-ẹjọ Magisreeti kan niluu Ilọrin lo paṣẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, pe ki wọn gbe e sahaamọ l’Oke-Kura, titi di ogunjọ, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.

Ahmed ni wọn fẹsun kan pe o n ba ọmọde to jẹ ọmọ lanlọọdu rẹ sun, eyi to lodi sofin.

Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe lati bii oṣu mẹfa sẹyin ni Ahmed ti n ki ọmọ naa mọlẹ, to n ba a laṣepọ.

Agbẹjọro ijọba, Akinjide Adisa, ni ki ile-ẹjọ ma gba beeli rẹ, ko wa lahaamọ nitori pe ẹṣẹ to ṣẹ buru jai.

Ọwọ palaba ọmọkunrin to n gbe ni Gaa-Odota yii ṣẹgi laipẹ yii, ti wọn si wọ ọ lọ si aagọ ọlọpaa to wa ni Adewọle, niluu Ilọrin.

ALAROYE tiẹ gbọ pe awọn obi olujẹjọ naa sa gbogbo akitiyan lati jẹ kawọn obi ọmọ naa jawọ lori ẹjọ ọhun, ṣugbọn awọn yẹn ta ku pe o gbọdọ jẹ iya to ba tọ si i.

Leave a Reply