Agbara ojo ṣọṣẹ nla l’Alimọṣọ, o gbe ọlọkada kan ati maṣinni rẹ lọ tefetefe

Faith Adebọla

Ojo arọọda to waye fun bii wakati mọkanla lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an yii ti da ẹmi ọlọkada kan legbodo, Ọgbẹni Abe ni wọn porukọ ọlọkada ọhun, latari bi ọgbara ojo ṣe wọ oun ati ọkada rẹ lọ lasiko to ja sinu omi nla naa, to si ṣe bẹẹ bomi lọ lagbegbe ibudokọ Ile-Epo, nijọba ibilẹ Alimọṣọ.
Yatọ si ti ọkunrin ọlọkada to doloogbe yii, awọn ile to ju igba (200) lọ ni omiyale naa ba lalejo, ti ọkọọkan awọn ile ọhun si gba apa loriṣiiriṣii, bii fẹnsi to wo, ogidi to san, ṣalanga to ri, ati bẹẹ bẹẹ lọ, lagbegbe ọhun titi de Agege.
Alaga ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nilẹ Yoruba, National Emergency Management Agency, NEMA, Ọgbẹni Ibrahim Farinloye, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọjọ Satide naa sọ pe, iku afọwọfa lo ṣẹlẹ si ọlọkada yii. O ni asiko tawọn eeyan duro, ti ko sẹni to laya lati wọnu ọgbara naa lo gun ọkada rẹ de, awọn eeyan si kilọ fun un lati maṣe dan wo pe oun n gun ọkada kọja omi naa, amọ ọlọkada naa ko gbọ, wọn lo sọ pe ko sewu.
Farinloye ni oju-ẹsẹ to gun alupupu rẹ wọnu ọgba yii ni maṣinni naa ti pana, to si taku, eyi lo mu ko nira fun lati du ara ẹ, niṣe ni ọgbara to n ṣan waa-waa naa gba oun ati maṣinni rẹ lọ.
Ọkunrin naa tun sọ pe ajọ NEMA ti bẹrẹ si i ṣabẹwo sawọn ile ti wọn fara gba ninu iṣẹlẹ omiyale yii. O lawọn ti ri i pe ọgbara naa ti sọ awọn eeyan di alainilelori, ti wọn si ti padanu awọn dukia wọn. Inu awọn ṣọọṣi mẹrin kan lagbegbe naa lawọn eeyan kan n tẹṣọ si sun latigba naa.
O ni ọga agba ajọ NEMA Ọgbẹni Mustapha Habib Ahmed ti paṣẹ ki wọn ki wọn ko awọn ipese amaratuni kan wa, bi i matirẹẹsi, aṣọ obinrin ati tawọn ọmọde, oogun apakokoro atawọn nnkan mi-in bẹẹ, ki wọn le ha a fawọn ti wọn nilo rẹ.
Bakan naa lo lawọn maa ṣe atunkọ awọn ile aladaani kọọkan, lati dena ipenija bii eyi lọjọ iwaju.

Leave a Reply