Ogbologboo ni Taiwo yii o, laarin wakati mẹjọ lo yi awọ Toyota Camry to ji n’Ilọrin pada si dudu

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu ọkunrin kan ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Abubakar Aliyu, baba ọlọmọ meji, fẹsun pe o ji mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry Saloon, alawọ pupa ti nọmba rẹ jẹ EPE 294 GT gbe niwaju ileegbe awọn akẹkọọ Fasiti KWASU, to wa niluu Malete, nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Babawale Zaid Afolabi, fi sita lo ti sọ pe Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ to kọja, ni Aliyu lọọ ji ọkọ ayọkẹlẹ naa, to si gba oju ferese kan wọle to fi dọgbọn mu kọkọrọ ọkọ ọhun, ni kete to ji ọkọ naa gbe tan lo gbe e lọ si ṣọọbu awọn ti wọn n ku mọto lọda. Adewunmi Taiwo Gabriel to wa lagbegbe Oko-Erin, niluu Ilọrin, si ba a yi awọ ọkọ naa pada si dudu laarin waki mẹjọ pere.

Afọlabi ni Aliyu ati Taiwo to kun mọto naa ti wa laahamọ bayii fun ẹsun ole jija, ti ọga agba ajọ naa nipinlẹ Kwara, Makinde Iskil Ayinla, si sọ pe iwadii yoo tẹsiwaju lati mọ igbesẹ to kan lori awọn afurasi mejeeji.

Leave a Reply