Ogoje awọn ọmọbinrin Naijiria ti ha si Saudi Arabia, ẹru ni wọn n fi wọn ṣe

Mejidijnlogoje (138) awọn ọmọ obinrin lati agbegbe gbogbo ni Naijiria ni wọn ti ha si Saudi Arabia bayii o, ko si si ohun meji ti wọn n fi wọn ṣe lọhun-un ju ẹru lo, ati awọn iṣẹ buruku mi-in ti ko ṣee sọ sita. Agbajọ awọn akọroyin kan ti wọn n ri si irin-ajo awọn ọmọ orilẹ-ede yii si ilẹ okeere (JIFORM) lo tu aṣiri yii sita.

Alaga ẹgbẹ yii, Ajibọla Abayọmi lo kede bẹẹ lanaa, ọjọ Aiku, Sannde. O ni awọn ti ri akọsilẹ nipa awọn ọmọbinrin Naijiria wọnyi ni Saudi, nitori awọn ti wọn gbọroo iṣẹ ti awọn n ṣe ti bẹrẹ si i fi iroyin nipa awọn ọmọ Naijiria ti wọn ba ha silẹ mi-in ranṣẹ sawọn. Lara awọn ti wọn ha si Saudi yii, ọmọbinrin Kano kan wa ninu wọn ti ọga rẹ ti gba pasipọọtu rẹ sọwọ, ti ko sọna to fi le jade kuro ni orilẹ-ede yii. Amina Idris loruko rẹ.

Ṣugbọn awon ọmọ Yoruba naa pọ nibẹ, ninu wọn si ni Atanda Idowu Esther ati Salawu Yetunde Victoria lati ipinle Ọyọ. Bẹẹ ni Gift Isreal Jonny to jẹ ọmọ ipinlẹ Rivers. Gbogbo won l ow an iSaudi, ti won s iti ha. Abayọmi ni awọn ti fi oruko wọn ranṣe sileeṣẹ ti n ri si ọrọ awọn ti wọn n ko awọn ọmọ  Naijiria lọ silẹ okeere lọna aitọ, ki wọn le mọ bi wọn yoo ti yọ wọn jade.

Leave a Reply