Ọgọrun-un meji oogun oloro lawọn eleyii ya mọgbẹẹ ni papakọ ofurufu Eko

Faith Adebọla, Eko

Bawọn afurasi ọdaran to n gbe ẹgboogi olori ṣe lawọn mọ ọn fi pamọ, bẹẹ lawọn ẹṣọ ajọ to n gbogun ti wọn NDLEA, naa lawọn mọ ọn wa, latari bi wọn ṣe mu awọn arinrin-ajo meji kan ti wọn fura si pe egboogi oloro wa lara wọn, Chukwudi Destiny ati Ezekiel Chibuzor. Ọgọrun-un meji o din mẹsan-an cocaine ati heroine ti wọn gbe mi lawọn afurasi naa ya mọgbẹẹ l’Ekoo.

Yatọ sawọn meji yii, awọn ejẹnti mẹrin ti wọn ṣiṣẹ kiko ẹru wọle, kiko ẹru jade, ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed tun lọwọ awọn agbofinro naa tẹ.

Alukoro apapọ fun ajọ to n gbogun ti lilo, gbigbe, gbigbin ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa (National Drug Law Enforcement Agency), Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, lo sọrọ yii di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Nigba to n ṣalaye bọrọ ọhun ṣe ṣẹlẹ ninu atẹjade kan, o ni lọjọ kẹtadinlogun, ọsu yii, iyẹn Satide to kọja, Ọgbẹni Ezekiel Chibuzor ba baalu Qatar Airline kan wọle lati orileede Brazil.

Nigba to kọja nibi ẹrọ ti wọn fi n ṣayẹwo awọn arinrin-ajo, ẹrọ naa bẹrẹ si i pariwo, to fi han pe Chibuzor lẹbọ lẹru, eyi lo mu ki wọn fi si yara kan, lẹyin wakati diẹ, o ya egboogi kokeeni mọkandinlọgọrun-un ti wọn we keekeekee mọgbẹẹ, nigba ti wọn si ko awọn kinni ọhun sori sikeeli (scale) diẹ lo ku ki iwọn rẹ to kilogiraamu mejila (11.55kg).

Babafẹmi ṣalaye pe ṣaaju akoko yii, lọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin yii, ọwọ ba Chukwudi Destiny nibi ti wọn ti n fi ẹrọ ṣayẹwo awọn to fẹẹ ba baluu ilẹ Ethiopia kan lọ sorileede Italy, ẹrọ naa lo ta awọn agbofinro lolobo ti wọn fi mọ pe ẹru ti wa nikun Destiny, igba toun naa si fẹẹ yagbẹ lẹyin wakati diẹ ti wọn ti fi i sinu yara ahamọ, egboogi heroine ti wọn di mọmbe mọmbe mejilelaaadọrun-un lo ya mọgbẹẹ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e.

Bakan naa ni Kọmanda ajọ NDLEA, Ahmadu Garba sọ pe awọn mu awọn ejẹnti kan ti wọn n ṣe onigbọwọ fawọn to n gbe egboogi oloro yii labẹ buka SAHCO ti wọn kọ fun wọn lẹgbẹẹ papakọ ofurufu naa. Egboogi koleeni ti iwọn rẹ le ni ẹgbẹrin kilogirammu (822,950 kg) ni wọn ka mọ wọn lọwọ, wọn ni wọn ṣẹṣẹ n ṣẹto bi wọn ṣe maa ko ẹru ofin ọhun sọda siluu Amẹrika ati London ni.

Nigba ti wọn n ṣiṣẹ iwadii, wọn laṣiiri tu pe ọmọ orileede Congo kan, Kayembe Kamba, ni wọn n lo lati gbe awọn egboogi ọhun, ọwọ si ti tẹ oun naa, o ti n darukọ awọn to n bẹ ẹ lọwẹ.

Babafẹmi ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, ati pe gbogbo awọn tọwọ tẹ yii maa ba ara wọn niwaju adajọ laipẹ, lati fimu kata ofin.

Leave a Reply