Ogun ayẹta ti babalawo ṣe fun ọrẹ ẹ lo fẹẹ dan wo, lo ba ge e lori ja l’Emure-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Iku ojiji to pa ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Ọgbẹni Sunday Joseph, jẹ iyalẹnu fun gbogbo olugbe to n gbe niluu Emure-Ekiti, nijọba ibilẹ Emure, nipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bi awọn to n gbe niluu naa ṣe sọ, wọn ni ọkunrin to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kogi yii lo lọọ ba ọrẹ rẹ kan to jẹ babalawo pe ko ṣe oogun okigbẹ, iyẹn oogun ti ada ko fi ni i ran oun tabi ti ẹnikan ba fi ada ge oun, ti ko ni i wọle s’ara oun.

Ọrẹ rẹ to jẹ ogbologboo babalawo ọhun torukọ rẹ n jẹ Joseph Kantala, ni wọn jọ n ṣiṣe agbẹ ni abule kan ti wọn n pe ni Adeboye, to wa loju ọna to lọ lati ilu Emure-Ekiti si Eporo.

Lasiko ti babalawo yii ṣe oogun okigbẹ yii fun un tan ti wọn si fẹẹ dan an wo lara oloogbe yii lo gbe ori rẹ silẹ lati dan oogun yii wo lati mọ boya o ṣiṣẹ

Ṣugbọn kaka ki oogun okigbẹ ti babalawo yii ṣe ṣiṣẹ, ẹjẹ lo bẹrẹ si i da lori Joseph, lo ba mu igbe nla b’ọnu. Igbe rẹ ti awọn eeyan agbegbe naa gbọ ni wọn fi sare jade lati waa wo ohun to ṣẹlẹ.

Awọn Amẹtekun to wa niluu naa ṣalaye fun akọroyin wa pe, “Awọn ọrẹ meji yii fẹẹ dan oogun okigbẹ ti babalawo to jẹ ọrẹ Joseph ṣe fun un wo ko too di pe o fun un ni, ṣugbọn ọrọ pada yiwọ nigba ti wọn n tẹẹsi oogun naa. Niṣe ni ada ti wọn lo fẹrẹ ge ori ọmọkunrin naa bọ silẹ, ti ẹjẹ si bo o ni gbogbo ara, to si gbabẹ ku ”

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmandanti Amọtẹkun ipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Olu Adewa, sọ pe iṣẹlẹ naa da jinni-jinni silẹ niluu naa.

O ṣalaye pe babalawo naa ti wa ni atimọle awọn, ati pe iwadii to peye ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa. O ṣeleri pe awọn yoo taari afurasi naa si awọn agbofinro ni kete ti iwadii ati itọpinpin wọn lori iṣẹlẹ naa ba pari.

Leave a Reply