Ogun eeyan tun kagbako iku ojiji ni Kaduna, wọn dana sun mọto ati ounjẹ wọn

Faith Adebọla

 O kere tan, ogun lara awọn eeyan to dagbere p’awọn n lọọ sun lalẹ ọjọ Satide lo jẹ pe ẹnu ibọn awọn jaduku afẹmiṣofo ni wọn ji si lọganjọ oru mọju ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti wọn si ṣe bẹẹ dagbere faye, nigba tawọn agbebọn naa yinbọn mọ wọn.

Yatọ si ti iku, awọn odoro ẹda naa tun dana sun ile wọn, wọn si sun awọn aka ounjẹ ti wọn n tọju ire-oko wọn si, ati awọn mọto pẹlu ọkada wọn.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto aabo abẹle rẹ, Ọgbẹni Samuel Aruwan, fi lede lọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, nipa iṣẹlẹ ibanujẹ naa.

“Ileeṣẹ ologun ati awọn ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti fi to ijọba ipinlẹ yii leti pe eeyan to ju ogun lo tun padanu ẹmi wọn ninu akọlu awọn janduku agbebọn ti wọn ya bo awọn abule kan nijọba ibilẹ Giwa, nipinlẹ Kaduna, loru mọju yii.

“Awọn abule ti wọn ṣakọlu si naa ni Kuaran Fawa, Marke ati Riheya. Awọn obilẹjẹ ẹda naa tun dana sunle, wọn sun mọto, ọkada, ati awọn ire oko wọn ti wọn tọju pamọ.

“Iṣẹlẹ yii ba gomina lọkan jẹ gidi, o si daro pẹlu mọlẹbi awọn to doloogbe, o si kẹdun pẹlu awọn to fara pa ninu akọlu yii, o ṣadura ki alaafia tete to agọ ara wọn.

“Bakan naa ni Gomina ti paṣẹ ki ajọ KADSEMA to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Kaduna bẹrẹ iwadii, ki wọn si jẹ kijọba mọ awọn idile to nilo iranlọwọ pajawiri, ati eto ti iranwọ naa yoo fi de ọdọ wọn.

“A maa gbe orukọ awọn ti ijamba yii ṣẹlẹ si jade laipẹ, a si ti ṣeto fawọn agbofinro lati maa lọ kaakiri gbogbo agbegbe yii atawọn ibomi-in to ṣee ṣe kiru akọlu bii eyi ti waye.”

Leave a Reply