Ogun miliọnu lawọn agbebọn to ji agbẹ mẹrin gbe n’Ifọn n beerewọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ko din lawọn agbẹ mẹrin tawọn ajinigbe kan tun ki mọlẹ, ti wọn si ji gbe sa lọ niluu Ute, lagbegbe Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
Awọn ajinigbe ọhun la gbọ pe wọn lọọ ka awọn agbẹ naa mọ ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ oojọ wọn lọwọ ninu oko wọn laaarọ kutukutu ọjọ ta a n sọ yii. 


Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lawọn agbebọn ọhun ṣẹṣẹ kan si ẹbi awọn agbẹ mẹrẹẹrin, ti wọn si ni ki wọn lọọ wa ogun miliọnu Naira wa ti wọn ba si fẹẹ ri awọn eeyan wọn laaye.
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro fi n da awọn araalu loju pe awọn ti n tọpasẹ awọn janduku naa, sibẹ, awọn ẹbi awọn ti wọn mu nigbekun ọhun ni wọn ni wọn ko duro lori eyi, wọn ni wọn ti n kowo nla jọ laarin ara wọn ki wọn le ri awọn eeyan wọn gba pada laipẹ.

Leave a Reply