Ogundeji, igbakeji gomina Kwara tẹlẹ, ti ku o

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Oloye Joel Ogundeji, ẹni to jẹ igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Kwara laarin ọdun 2003 si 2011, ti jade laye, lẹyin aisan ranpẹ.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ yii, ni baba naa dagbere faye. Ogundeji jẹ igbakeji gomina ni akoko ti Dokita Abubakar Bukọla Saraki n ṣejọba laarin ọdun 2003 si ọdun 2011.

Gomina ipinlẹ Kwara Abdulrahman Abdulrasaq, ti kẹdun iku oloogbe ọhun, o si juwe iku rẹ gẹgẹ bii adanu nla fun mọlẹbi rẹ ati ipinlẹ Kwara lapapọ. Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, fi sita ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni gomina ti ni oun kẹdun pẹlu mọlẹbi oloogbe ati gbogbo eniyan ijọba ibilẹ Isin lapapọ. Bakan naa lo gba adura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere, ko si rọ awọn mọlẹbi loju.

Leave a Reply