Florence Babaṣọla
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti kede Ọmọọba Akeem Oluṣayọ Ogungbangbe gẹgẹ bii Ọwaloko ti Iloko-Ijeṣa, nijọba ibilẹ Oriade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Igbesẹ yii waye lẹyin awuyewuye to ti fi odidi ọdun mẹsan-an waye lori ẹni ti yoo bọ sori itẹ naa lẹyin ti Ọwaloko ana, Ọba Ọladele Ọlashore, waja.
Lẹyin ti Ọba Ọlashore waja loṣu kẹfa, ọdun 2012, awọn afọbajẹ mọkanla ninu awọn mẹtala ni wọn fọwọ si iyansipo Ọmọọba Ogungbangbe, ṣugbọn ijọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ko kede orukọ ọkunrin naa latari oniruuru wahala to ṣu yọ nigba naa.
Amọ lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun to waye lọjọ Iṣẹgun, Kọmiṣanna feto iroyin, Funkẹ Ẹgbẹmọde, kede orukọ Ọmọọba Ogungbangbe, o ni iyansipo naa yoo si bẹrẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin ti a wa yii.
Gẹgẹ bi Ẹgbẹmọde ṣe sọ, igbesẹ naa jẹ ọkan lara awọn igbesẹ Gomina Oyetọla lati ri i pe alaafia ati ifọkanbalẹ wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, paapaa, lawọn agbegbe ti awuyewuye ti n waye lori ọrọ ọba.